ILOSIWAJU ALAILEGBE LO JE MI LOGUN - KEHINDE TAIWO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, October 2, 2018

ILOSIWAJU ALAILEGBE LO JE MI LOGUN - KEHINDE TAIWO

Okan lara awon oludije sipo asofin agba (seneto) lorileede yi labe egbe oselu PDP, Ogbeni Kehinde Taiwo ti seleri idagbasoke alailegbe fawon ara Ota ati agbegbe agbegbe e lodun 2019, iyen bi won ba dibo yan oun lati loo soju won ninu eto idibo to n bo lona.


Ogbeni Kehinde Taiwo lo soro yi lasiko to n b'AWIKONKO soro lai pe yi niluu Abeokuta nibi idibo pamari ti won se lati yan adije sipo gomina labe egbe oselu naa lodun 2019, iyen Onarebu Oladipupo Adebutu, topo awon eeyan mo si LADO.

Taiwo so pe kii se pe oun dee de jade lati gbe apoti ipo naa, sugbon ife toun ni sawon toun fe e loo soju, iyen awon eeyan oun lo mu koun pinu lati jade, paapaa nigba tawon to won n ran lo ko se ife awon to dibo yan an sipo.

O tesiwaju pe "Mo fe e rii daju pe gbogbo eto tijoba n fi sile fun won n te won lowo, gbogbo awon idagbasoke to ye ko kan wa lagbegbe ti mo ti fe e jade, ni mo fe e ko te wa lowo nitori pe a ko lawon asoju to n se e fun wa, mo fe mu iyato rere wa pe nigba ti n ba de be, won mo iyato laarin emi atawon ta a ti n yan tipe.

"Ilosiwaju lo je mi logun pupo, kawon eeyan mi je mudunmudun ijoba awaarawa bii opopona to ja geere, agbegbe to fokanbale, omi gidi, eto ilera to peye, eto eko to ye kooro. Nigba ta a wa nileewe alakobere ati girama, a mo awon nnkan ta a je igbadun e, sugbon ko ri bee mo bayii, asiko re e lati ja fun awon nnkan yi pada.

"Ni temi o, mi o ro pe eni to n soju wa lowolowo bayii ti mu iyato gidi gan de ba wa latigba to ti lo soju wa, ko tii wa a dawo le ohunkohun, nnkan to wa nibe ko too lo naa lo si wa nibe titi dasiko yii. Ko si tii pada yoju sawon eeyan to dibo fun, ko tii mu awon ileri e se fun won. 

"Kii se pe mo n bu enu ate luu, sugbon to ba je pe o n se daadaa, awon eeyan ko nii too leemeji ki won too dibo yan an leekeji. Nnkan to le mu kawon araalu maa pariwo pe elomin in lawon fe, o ti fi han daju pe eni naa ti kuna patapata ni. Iyato to foju han ni mo fe e mu de ba awon ti mo fe w loo soju won."

Bakan nigba to n soro lori bawpn eeyan se two gba a pelu ipinu to ni fun won, okunrin naa so pe "Asiko oselu awaarawa la wa yi, oni kaluku ni won leto lati dibo, ki won si tun dibo fun won, bo tile je pe beeyan ba fee jade dupo, o ni lati loo bawon eeyan e soro, ko si so ipinu e fun won, awon eeyan yi gan an lo maa pinu lati yan eni ti won fe. 

"A ti se nnkan ta a le se, a ti kaakiri awon agbegbe ati igberiko lati bawon ta a fe e loo soju soro, paapaa awon ijoba ibile wa la ti loo yoju sii, inu gbogbo won lo dun si nnkan ta a ni fun won."

Nipa ti eto idibo abele, iyen pamari ti won fi yan LADO gege bi eni ti yoo jade dupo gomina labe egbe oselu PDP, Kehinde Taiwo so pe "Eto idibo pamari to bere yi je eyi to dara pupo, ko da a, mo fe w le so pe iru e ko tii sele ri, gbogbo eeyan lo setan lati fowosowopo rii daju pe adije sipo gomina labe egbe oselu wa, PDP, iyen Onarebu Oladipupo Adebutu lo wole lodun to n bo. 

"Gbogbo aisedeede ijoba to wa nita yi, ni LADO fee tun se. Gbogbo awon eto ti ko kan mekunnu, bi oju opopona ko se dara ni LADO fe e pada se fawon araalu."

O wa a gbawon araalu lamonran pe ki won ma tan ara won je, ki won si ma je kenikeni tan won je, ati pe won gbodo mo nnkan ti won fe, nitori naa, erongba wi pe ki won maa gba owo ki won too di bo fun eni ti ipo ko to sii maa n sakoba fun ojo iwaju rere ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI