Pasito ijo
Latter Rain, Tunde Bakare ti sapejuwe Alaaji Atiku Abubakar, eni ti egbe oselu
PDP fe lo fun idije-dupo aare lodun 2019 gege bi eni to kunju osunwon, to si le
koju Aare Buhari, toro ba doju ogbagade tan.
Ojise Olorun yii
soro ohun ni soosi e lasiko to soro lori ayeye ominira odun mejidinlogota ti
orile-ede Nigeria se.
Bakare ti so pe,
“Mo ki Atiku Abubakar ku oriire, bi egbe oselu PDP se fe lo o fun idije-dupo
aare, eyi yoo je ki eto idibo odun to n bo larinrin daadaa.
“Mo gbagbo wi pe
Aare Muhammed Buhari naa yoo lo ipo e gege bi adari orile-ede yii lati fi sise
daadaa si i ko le rorun fun un lati pada wa leekan si i. Bee ni mo tun nigbagbo
wi pe, Atiku Abubakar naa ko ni i gba a lero, nise ni won yoo jo na an tan bii
owo. Eni to to gba-n-gba sun loye lawon mejeeji, eyi gan-an ni yoo mu idibo
odun 2019 larinrin.”
Pasito Tunde
Bakare te siwaju pe, ki i se pe oun n lukoro fun un, sugbon ti a ba n so nipa
eni to kunju osunwon daadaa laarin awon ti won jo dije pamari, ati pe Atiku
Abubakar ni enu e tole daadaa laarin gbogbo eya meteeta ti ede won han ju ni
Nigeria, iyen WAZOBIA.
O wa fi kun un
oro e wi pe, “Awon araalu ni yoo so ibi ti won fe lo lori awon mejeeji nitori
yoo soro lati so pe Atiku ni yoo jawe olubori tabi fidi remi ninu ibo ohun,
nitori eni ti iriri e kun daadaa ni. Akoko, o ti lo odun mejo ri gege bi
igbakeji aare orile-ede yii, bee lo tun je omoleyin Yar-Adua, to si n tele
ilana ti iyen fi sile.”
Bakan naa lo tun
so pe, onisowo to ti gbiyanju daadaa ni okunrin naa n se, ti a ba n so nipa
keeyan o mo nipa oro aje.
Siwaju si i,
Bakare so pe, “Awon abuda ti mo so soke yii nikan ko lo maa n mu eeyan jawe
olubori ninu ibo o, nitori ohun to wa leyin efa ju eje lo daadaa.”
Okunrin ojise
Olorun yii ti wa ro awon omo egbe oselu PDP lati mura daadaa ki won si je ki
awon omo Nigeria mo pe won ti tuuba ninu iwa ajebanu, ati pe isoro ti won ko
awon omo orile-ede yii si fun odun merindinlogun ti won fi sejoba Nigeria, iru
igbe aye bee ko tun ni i waye mo.
Lori egbe oselu
APC, Tunde Bakaere so pe ki i se pe oun korira egbe naa, o ni, loooto ni joba n
gbiyanju, sugbon bi won se so pe awon n sise to, sibe opo eeyan orile-ede yii
ni won n pariwo, ti ara n ni awon eeyan gidigidi. O ni, igba die to ku ki eto
idibo mi-in waye yii, nise ni won gbodo lo anfaaani die to ku lati fi sise ki
irorun ati idekun le ba awon eeyan Nigeria , ki nnkan le senuure fun won lodun
2019 ninu ibo to n bo.”
Lakootan, Bakare
ti so pe asiko niyi fun gbogbo omo Nigeria lati yan olori ti yoo ko irorun ba
won, ti igbe aye won yoo le ni ilosiwaju rere bi eto idibo se n sunmo etile
yii.