Latari wahala to be sile nibi idibo abele, iyen pamari egbe oselu APC nipinle Ogun, egbe naa ti kede sita pe AbdulKabir Adekunle Akinlade ni won dibo yan gege bi adije sipo gomina ipinle Ogun lodun 2019.
Olu-ileese egbe oselu APC to wa ladugbo Iyana-Mosuari niluu Abeokuta ni won ti kede sita ni nnkan bi aago meji osan onii, Wesde pe awon omo egbe naa to ku die ko pe egberun lona igba lo dibo yan Akinlade ti won tun n pe ni Triple A.
Ibo 190,987 la gbo pe awon omo egbe di fun Akinlade lati fi jawe olubori, nigba ti Omoba Dapo Abiodun ni ibo egberun meta le die, 3,148.
Ekunrere iroyin naa n bo lai pe.
No comments:
Post a Comment