Lati aaro ijeta, lariwo naa ti n lo laarin
igboro pe gomina ipinle Ekiti to n kopa wole bayii, Ogbeni Peter Ayodele Fayose
fee fi egbe oselu PDP sile lo sinu egbe mi-in.
Ohun tawon kan tie so ni pe nitori awon EFCC ti n won dode e lokunrin naa se
fee sa lo sinu egbe APC. Sugbon, Fayose ti soro, o ti so pe ko si ohun ti yoo
gbe oun kuro ninu egbe PDP lo sinu egbe mi-in laelae, o ni titi aye loun yoo wa
ninu egbe naa.Alaye ti okunrin naa se ni pe oun yoo pawopo pelu oludije ipo aare labe egbe oselu PDP, Alaaji Atiku Abubakar gbajoba lowo Buhari lodun to n bo ni.
Pelu ohun ti Fayose, tawon mi-in tun maa n pe ni Oshokomole so yii, o ti fihan pe ko nibi kankan to n lo, o si wa digbi ninu egbe PDP
Lati: OJUTOLE-TOKO