EYI NI BI FAYEMI SE DI GOMINA IPINLE EKITI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, October 17, 2018

EYI NI BI FAYEMI SE DI GOMINA IPINLE EKITI

 Lojo Tusde ana ni itan mi-in tun sele l’Ekiti, bi won se n bura fun gomina tuntun, John Kayode Fayemi, bee ni ajo EFCC tewo gba Peter Ayodele Fayose niluu Abuja.

Okan di gomina, ikeji kuro nipo gomina, bee lo di alejo nla lodo ajo EFCC lati dahun awon ibeere to ni se pelu iwa ajebanu atawon iwa odaran mi-in.

Laaro kutu lawon eeyan ti n wo lo si gbongan nla Ekiti Parapo Pavillion niluu Ado-Ekiti nibi ti won ti bura fun Kayode Fayemi, gege bi gomina tuntun nipinle naa.

Bi okunrin oloselu yii ti bo sori apere nibi ti ero agbagbe, iyen microphone wa, ohun akoko to koko so fawon eeyan ipinle Ekiti ni pe, lati wakati yii lo, igba otun ti de.

Lowo asale, ninu alaye to se lori ero amohunmaworan Channels television lo ti so pe, oun ti setan lati sise takuntakun lori bi ise agbe yoo se ni ilosiwaju nla nipinle naa.

Kayode Fayemi so pe, gbogbo ona ti ise agbe yoo gba fi wulo fun ati olori ati elemu nipinle naa ni ijoba setan bayi lati mojuto.

Siwaju si i, o ni lori ise agbe ti oun n so nipa e yii, awon odo paapaa ni ise gidi lati se, ti ara yoo si tu kaluku.

Ohun mi-in ti gomina ohun tun menuba ni eto eko to yanranti, o ni ijoba oun yoo mojuto oro eko, ti Ekiti yoo pada si aaye pataki to wa ti a ba n so nipa eto eko gidi ni Nigeria. Ohun mi-in ti gomina yii tun loun yoo sise le lori ni bi owo osu awon osise yoo se te won lowo, paapaa eyi ti ijoba to sese ko gba wole je won. Bakan naa lo so pe, ijoba naa ko ni i fowo yepere mu owo osu won nipinle naa.

Siwaju si i, Fayemi tun so pe, ti ijoba ba n ri owo osu san deede, eyi gan-an lo le mu awujo tete dagbasoke, nitori owo ti won ba n gba naa ni yoo maa mu oro aje ru gogo si i, ti ara yoo de kaluku laarin ilu.

Bakan naa lo tun so pe ise takuntakun nijoba oun yoo se lori oro ilera araalu, ati pe awon ohun amayederun lorisirisi yoo je ohun amojuto gidi fun idagbasoke ipinle Ekiti. 

Te o ba gbagbe, igba keji ree ti gomina tuntun yii yoo pada sile ijoba ni Ado Ekiti. Odun 2014 ni Ayodele Fayose fidi e janle lasiko to gbiyanju lati dije ko le ba a sejoba ipinle ohun leekan si i, sugbon nise ni ibo ti won di lodun naa lohun-un ko se e loore rara.

Ni bayii to ti pada sile ijoba, o ti so pe igbe aye irorun alailegbe ni ki awon omo Ekiti maa reti bayii.

Sa o, bi Fayemi se n wole so o sile ijoba l’Ado-Ekiti, ninu galo awon EFCC ni Fayose wo lo ni tie. Okan bo sipo gomina, ikeji kuro nipo gomina, ileeese to n sewadii awon to ba kowo ilu je tabi huwa odaran mi-in; lodo won gan an ni Fayose gba lo. Nibi ti gbogbo oro yii yoo yori si, e o maa ba a pade lori ikanni yii.

PÍN-IN KÁÀKIRI