Ileese to
gbogunti sise owo kumo-kumo, iyen EFCC ti kede sita pe owo awon ti te gendekunrin
kan ti ko nise meju ju ko maa lu jibiti lori ero ayelujara lo, to si ti so
opolopo awon eeyan die dun-arinle.
Oke Omoniyi
Benjamin loruko gendekunrin naa, omodun metalelogun (33) ni won pe e. Ilu
Efon-Alaaye nipinle Ekiti lowo ti te e.
Lara awon
nnkan ti won ri gba lowo e ni orisirisi iwe sowedowo, moto biginni-boginni
atawon ayederu iwe orisirisi.