Gbajumo
sorosoro ori redio ati telifisan nni, Oloye Abiodun Fagboro tawon eeyan tun maa
n pe ni Jenera Ofasia (General Overseer) ori redio ti pariwo sita fawon araalu
pe oun kii se wolii to n riran tabi eyi to n so asotele, nitori pe kii se ise
ti Olorun fi ran oun.
Aaro
ojo Sande to koja yi ni ogbontarigi sorosoro naa soro yi lori redio lati fi tawon
araalu lolobo latari bo se so pe awon kan fi oruko oun lu awon eeyan kan ni
jibiti latari iran eke ati asotele iro ti won ni won ri si won.
AWIKONKO
gbo pe lose to koja yi lawon kan loo fi oruko okunrin naa lu awon eeyan ni
jibiti owo to po. Ohun ti won so ni pe awon ni omose Abey Fagboro, iyen Jenera
Ofasia, oun lo si ran awon nise lati loo jise iran naa.
Agbegbe
Kola si Sango (Tollgate) la gbo pe awon onise buruku naa wa, ti won si ti lu
opolopo awon araalu ni jibiti owo ati ara. Awon iran to m deru ba awon eeyan la
gbo pe awon odaran naa maa n je fawon ti won ba fe e lu ni jibiti.
Nigba
to n soro, Fagboro so pe ise sorosoro, ipolowo, alagbata atawon ise to nii se
pelu redio ni Olorun fi ran oun, kii se ise wolii to n jise eke tabi riran.
O wa
ro awon araalu pe biru awon eeyan ba yii ba tun pade won, tabi pe won lori
foonu, ki won tete fi to awon agbofinro leti ki won le ti ese ofin bo oro won.