EGBE PVC NAIJA KO NI OLUDIJE SIPO OSELU KANKAN – DOKITA AKINYEMI PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, October 17, 2018

EGBE PVC NAIJA KO NI OLUDIJE SIPO OSELU KANKAN – DOKITA AKINYEMI PARIWO SITA

Alaga egbe kan to nii se pelu oro oselu, Project Victory Call (PVC Naija), Dokita Bolaji Akinyemi ti pariwo sita fawon omo Naijiria pe egbe awon ko ni adije sipo oselu tawon fe e sagbateru e ninu idibo odun 2019 to n bo lona yii.

Dokita Akinyemi lo soro naa niluu Eko lojo Monde to koja yi nibi ipade ti egbe naa se lati fi saami ayeye odun awon akekoo kaakiri agbaye.

O ni looto, egbe awon, PVC Naijia nii se pelu oro oselu, sugbon sibe, lowolowo bayii, awon ko ni adije sipo oselu kankan tawon fe e sagbateru e ninu idibo odun 2019 to n bo lona yii, ati pe awon si n wa ona tawon yoo gba lati fi bawon eeyan soro, paapaa awon odo, ki won le maa gbaradi fun ipo Aare.

O ni odun 2050 lawon n wo bayii pe awon odo asiko yi ni won yoo wa lori ipo Aare orileede Naijiria nitori pe gbogbo igbese tawon n gbe, pelu ilana ati ofin tawon fi da egbe PVC Naija sile ni pe kawon odo gba ipo Aare atawon ipo to se pataki ninu ijoba orileede yii.

Dokita Akinyemi ni kawon too fowosowopo pelu egbe oselu tabi adije, awon yoo koko wo ipinu ati ilana ti egbe naa ni fawon araalu, leyin yen lawon yoo wo oloselu to ba fe e jade dupo lati mo ipinu ati ife to ni sawon araalu. O ni bawon ba ri nnkan tawon n fe yi tan, ko si nnkan to ni kawon ma sagbateru egbe oselu tabi oloselu to ba fe e jade dupo to ba wuu.

Bee lo so pe bi egbe oselu tabi oloselu ko ba lowo lowo, to ba ni ojo iwaju rere fawon araalu, to si le tan isoro awon araalu pelu igbasoke alailegbe, ko si nnkan to da awon duro lati ma ma gbaruku ti won nitori pe ilosiwaju orileede Naijiria lawon n fe.
Saaju asiko yi ni Dokita Bolaji Akinyemi so pe ki orileede Naijiria to le ni igbala, a gbodo gbe igbese lona to ye, nitori pe a fi ki agbekale idanilekoo wa fawon oludibo ti ko kawe, awon agbe, awon oni-owo, olokoowo, awon babaloja ati iyalaje, nitori pe awon ni obi awon akekoo to ni ojoola rere.

Bee lo so pe a gbodo fun awon odo laaye lati pinu nnkan ti won ba fe, ki ojoola won le ni itunmo to ye, ki atunse ati ojo iwaju rere si le de ba orileede Naijiria.

O ni pe ile Afrika wa leyin, ko tunmo si pe won ko ni awon ohun amusoro ati amusagbara nitori pe orileede Naijiria nikan ni awon nnkan wonyii ju gbogbo ile Europe lo.

Saaju asiko yi, ninu oro ikinni kaabo e, Arabinrin Derin kappo to je alakoso egbe naa nipinle Eko lo ti so pe awon ti n gbaradi lati rii pe odo gbajoba orileede Naijiria, nitori pe asiko re e fun won lati gba eto won.

PÍN-IN KÁÀKIRI