Olori
ile igbimo asofin ipinle Ogun, Omoba Suraj Ishola Adekunbi ti rawo ebe sijoba
apapo lati wa nnkan se si opopona Eko siluu Abeokuta, paapaa opopona Agbara si
Sango Ota, latari bo se n baa won moto je lojoojumo.
Suraj
Adekunbi lo rawo ebe naa lai pe yi si Komisana foro ise ati idagbsoke ilu,
Olalekan Adegbite pe ko mo bi yoo se ba ileese to n ri soro ina, ise ati
ilee’gbe lati le wa iyanju si awon opopona naa latari bo se n din eto oro aje
awon agbegbe naa ku.
Olori
ile igbimo asofin so pe bo tile je pe ijoba ipinle ati ijoba apapo ti n sise
takuntakun lori awon opopona yi, sugbon sibe, se lo ye ki n wa nnkan se lati
rii pe won se ibi ti omi yoo maa gba koja, ti ko sin ii je ki omi tabi agbara
ya wo oju opopona bi ojo ba ti ro.
O ni
ojo to n ya wo opopona lo fa tawon ona naa fi n ba je, nitori naa, lati le
dekun wahala tawon awako n dojuko lawon opopona yi, a fi kawon ijoba mejeeji
tete gbe igbese ti yoo fopin si isoro naa.