BABA YORUBA GBAKOSO IWE IROYIN AWIKONKO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, October 6, 2018

BABA YORUBA GBAKOSO IWE IROYIN AWIKONKO

Bo tile je pe lati bi osu mefa seyin ni oludasile iwe iroyin AWIKONKO, Ogbeni Gbenga Oladipupo ati Ogbeni Ismail Babalola topo awon eeyan mo si Baba Yoruba ti jo wa lori oro bi idagbasoke, ilosiwaju alailegbe yoo se de ba iwe iroyin AWIKONKO.


Ti orisirisi ipade ati oro asoyepo si ti waye nipa bi AWIKONKO yoo tun se gun oke agba ju ti tele lo, sugbon ni bayii, gbogbo eto lo ti pari, ti Ogbeni Babalola ati Ogbeni Oladipupo si ti towo bo iwe adehun.

Iwe iroyin AWIKONKO je iwe iroyin ori ero ayelujara, to si n royin fun igbeleke otito ati awijare, odun 2016 ni iroyin Awikonko bere lori ero ayelujara pelu buloogi (blog), iyen www.iroyinawikonko.blogspot.com, leyin osu mefa ni ayipada tuntun de baa, to si di website to wa lonii, www.awikonko.com.ng.

Ko din ni orileede marundinlogbon yato si Naijiria to n ka iwe iroyin AWIKONKO lagbaye lojoojumo, tawon eeyan si n se sadankata e. Lara awon orileede naa ni: United Kingdom, Peru, Canada, South Africa, United States of America, Brazil, Norway, Ghana, Benin Republic, Russia, Argentina, Germany, England, Kenya, India, Italy, Netherland, France, Tanzania atawon min in.

Nigba to n soro nipa idi to fi gbe iwe iroyin AWIKONKO sile fun Ogbeni Ismail Babalola, Ogbeni Gbenga Oladipupo je ko di mi mo pe looto ni ko rorun lati gbe nnkan topo awon eeyan ti mo eeyan mo sile, sugbon fun itesiwaju nipa ise tuntun to sese gba ni.

Okunrin omo bibi ilu Abeokuta naa tun so pe lati le dojuko ise iwe iroyin Yoruba kan to gba daadaa, ti ko si see se keeyan ko irin meji sinu ina leekan soso, okan yoo di okan lowo, idi ni yii to fi loun gbe akoso iwe iroyin naa sile fun eni to nigbagbo ninu e pe yoo dari e daadaa.

Oladipupo tun tesiwaju pe "Mo dupe pe nigba ti mo bere AWIKONKO, opo awon eeyan ni won bu enu ate luu pe mi o le saseyori ninu e, gbogbo ipa ati agbara mi ni mo sa lati le je kawon eeyan tewo gba a, ti Olorun si gbo adura naa.

"E ma je ki n tan yin, pupo ninu awon ti won foju tembelu mi nigba naa ni won n bebe pe awon fe ki AWIKONKO gbe iroyin awon lonii, awon eeyan tun n gbe ipolowo fun wa, ko da a, ijoba ipinle Ogun mo iroyin AWIKONKO.

"Bi mo se n se AWIKONKO naa ni mo tun n sise fun iwe iroyin kan ti mi o ni fe e daruko e, sugbon ko rorun lati ti irin meji bo inu ina leekan soso, idi ni yii ti mo fi pinu lati wa eni ti yoo tesiwaju e, ti mo si nigbagbo pe oga mi ti mo gbe isakoso e sile fun yoo sabojuto e daadaa.

"O ti le lodun merin ti mo ti mo Ogbeni Babalola, ko da a, awon ni won ko mi ni ede Yoruba nigba ti mo je akekoo nileewe gbogbonise ti Moshood Abiola (MAPOLY, Abeokuta). Awokose ni Ogbeni Babalola je fun mi, ti won si ti ko ipa to joju ninu igbesi aye mi. Mi o le kabamo pe mo gbe sile fun won nitori pe won mo tinu teyin nipa ede ati iroyin abinibi, Yoruba."

Ogbeni Babalola topo awon eeyan tun mo si Baba Yoruba nigba toun naa n soro, o ni inu oun dun lati gbakoso iwe iroyin AWIKONKO, bo tile je pe osu to koja lohun, August ni eto naa ti pari, sugbon oun loun da a duro di asiko.

O ni igbese lati rii pe awon ayipada rere de ba iwe iroyin AWIKONKO fun igbadun awon ololufe atawon to n ka, eyi ti yoo je ki won mo pataki ede ati asa Yoruba. Bee lo so pe igbeleke otito ati awijare ti AWIKONKO fi n gbe iroyin jade ko nii ye, yoo tun gberegejige sii ni.

Babalola wa a fidi e mule pe o see se lai pe, iwe iroyin AWIKONKO yoo di iwe iroyin tawon eeyan yoo maa ri ka ninu iwe, eyi ti yoo fawon ti ko mo nipa ero ayelujara lanfaani lati maa ka.

PÍN-IN KÁÀKIRI