AMOSU FIPA BA OMODO E SUN, LO BA TUN LE E JADE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 29, 2018

AMOSU FIPA BA OMODO E SUN, LO BA TUN LE E JADE

Kani ileese olopaa nipinle Ogun ko tete gbe igbese lati loo ka baale ile agba radarada kan ti won pe oruko e ni Abiodun Amosu mole ni, o see se ko ti na papa bora, ati pe kani o mo pe asiri oun maa pada tu sawon olopaa lowo ni, o le ti wa woroko fi s'ada.


Omodo e, omodun merindinlogun (16) la gbo pe Amosu fipa ja ibale e lojo Tosde ose to koja yi, to tun lu omo naa nilukulu leyin to ba a sun tan, bee lo tun le e jade.

Asiko ti won ni iyawo baba agbaaya eni odun mejilelogoji naa lo siluu Eko la gbo pe o fipa ba omodebinrin naa ta a foruko bo lasiri lo po, to si tun le e jade sita pe ko maa ba ti e lo.

Nibi tomodebinrin omo bibi ipinle Benue naa ti n sunkun kaakiri igboro Abeokuta lo ti salabapade okan lara awon ajefeto-omo-eeyan, tiyen si muu gba tesan olopaa lo lati fi to won leti.

Lesekese lawon olopaa naa ti gbera lati loo ka baale ile naa mole, ti won si gbe omodebinrin yi lo osibitu lati sayewo fun, nibi ti won ti sakiyesi pe won sese fipa ja ibale e ni.

Ise esu ni Amosu si n so pe o sun oun de ibi iwa buruku naa, to si n bebe pe ki won dariji oun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI