Odu ni Omobabinrin Ajike Atanda Abosede, eni topo awon eeyan mo si Ajike Seranko-Seniyan tabi Ajike Eran Iya Osogbo, kii sai mo f'oloko. Odun 1980 ni Ajike bere ise tiata pelu oga e to pe ni Ori Ade, eni to tun je egbon e. Omo bibi Idiroko nipinle Ogun ni Ajike, sugbon ilu Osogbo nipinle Osun lo fi sebugbe titi di asiko yii, bo tile je pe omo bibi ilu Ede ni mama to bii lomo je.
Lai pe yi ni Omobabinrin Ajike Atanda Abosede b'AWIKONKO soro nipa bo se bere ise tiata ati awon ibi ti ise naa ti gbe e de, paapaa awon fiimu e to ti se funra e, pelu bo se pade Oloogbe Ajileye topo awon eeyan nigbagbo oun lo ko Ajike nise tiata.
Ajike ti wa a je ko di mi mo pe Oloogbe Ajike kii se oga oun, oun ko si si ninu egbe osere tiata ti oloogbe naa da sile. Sababi ni boun se pade Oloogbe Ajileye je, ko too ba won kopa ninu awon fiimu alaragbayida to mi gbogbo ilu titi nigba nigba naa, iyen fiimu Seranko-Seniyan ati Eran-Iya-Osogbo. Wonyii lawon ohun ti Ajike b'AWIKONKO so ninu iforowero naa.
AWIKONKO: Oruko
yin?
AJIKE: Oruko mi ni
Omoba Ajike Atanda Abosede tawon eeyan mo si Iya Sango, Iya Osun, sugbon igba
ti mo kopa ninu Eran Iya Osogbo ni opo awon eeyan ti n pe mi ni Ajike Seranko
Seniyan.
AWIKONKO: Igba
wo gan an le bere ise tiata?
AJIKE: Mo ti bere
ise yi tipe, ki Olorun pin wa lere, o ti le die logbon odun bayii. Odun 1980 ni
mo bere pelu egbe oga mi, Ori Ade Theatre Group to je omo bibi ilu Idiroko, Ori
Ade ni akobi baba mi. Odo e ni mo ti bere ise tiata ko too di pe mo wa n gbe
niluu mama mi, Ede nipinle Osun. Omo bibi ilu Idoroko nipinle Ogun ni mi nitori
pe ibe ni Baba mi ti wa, Ede ni mama mi ti wa. Mo se kekere die n'Idiroko ki n
to lo si Osun.
AWIKONKO: Ki
le ri nibe te e fi darapo mo ise tiata?
AJIKE: Nnkan to
wun mi ni pe lati kekere ni mo ti maa n dawon eeyan laraya, paapaa nigba ti mo
wa nileewe, tawon eeyan si maa n gboriyin fun mi. Igba to ya ti Booda mi naa
bere tiata n'Idiroko, mo wa bere sii bawon sise. Lawon igba yen, ere oloogun
ati Erelu ni won maa n fi mi se. A loo se ere kan nigba yen to je pe won yinbon
fun mi, to se mi lese ninu, osibitu ni mo ti laju lojo keta. Igba yen gan ni mo
ti n rii pe ona ti mo fe e gba ni mo dojuko yen. Nipa bee, igba ti mo de ipinle
Osun, mo sese wa a ri ara mi daadaa pe ise ti Olorun fi ran mi nise tiata.
AWIKONKO: Egbe
Tiata Oloogbe Ajileye lawon eeyan fi mo yin, igba wo le darapo mo won?
AJIKE: E seun, se
e ri ise tiata ta n se yi, ti won ba rii pe ipa kan wa nibe, iwo leni to le se
daadaa, ko si ani-ani, won maa pe e. Mi o kii se omo egbe Oloogbe Ajileye rara,
sugbon won pe mi pe ki n wa a sise yen ni, inu mi si dun si, mo fi gbogbo ara
ba won se e.
AWIKONKO: Fiimu
meloo le ti kopa ninu e ati pe ewo gan an lp gbe e yin sita?
AJIKE: Mi o le ka
fiimu ti mo ti kopa ninu e tan, sugbon eyi ti mo le so pe o gbe mi jade ju ni
Eran Iya Osogbo ti Oloogbe Ajileye se e. Ki Eran Iya Osogbo too de, mo ti se
Alapooka ti Oloogbe Yomi Ogunmola se. Mo se ninu Lagidigba ti mo se jagunjagun,
Yemi Adegunju lo nii; leyin e la se Ogun Abele Ti Je, igba ta a kuro nibe la
sese loo se Eran Iya Osogbo. Emi gangan ko lo ye ki n ko ipa yen, sugbon
Audition ti won se ni won fi mu mi, mo si dupe lowo Olorun nigba yen. Bi a se n
pari Eran Iya Osogbo yen la tun se Seranko Seniyan. Lara awon min tun ni Olowo
Sile, Aso Funfun, Fiwasaye, Omo Alhaja, abbl, eyi to n bo lona ni Abuke Osin.
AWIKONKO: Yato
si ise tiata, ise wo le tun n se e?
AJIKE: Looto ni,
dokita tibile (traditional doctor) ni mi. Mo n toju olomo were, boya omode ko
rin, boya eeyan ni aisan ropa-rose, iyen sirooki, mo maa n toju won. Mo n gba
ebi fawon alaboyun to ba fe e bimo, Oluwa si n gba fun mi, nitori pe kii se
agbara mi, bi ko se aanu Olorun.
AWIKONKO: Iha
wo ni oko yin ko si ise yi?
AJIKE: Oko mi kii
se elere ori itage, bee ni kii se tiata. Ko binu si ise ti mo n se yi. Oga
olopaa ni oko mi, o si n faaye gba mi.
AWIKONKO: Sinima
meloo leyin funra yin ti gbe jade?
AJIKE: Ko tii ju
meta lo ti mo ti gbe jade, awon naa ni Remilekun, Aje Pupa ati Owo n Wa Mi to
je pe omo mi lo se e.
AWIKONKO: Ki
le le pe gege bi aseyori nidi ise yii?
AJIKE: Lara awon
nnkan ti mo ti ri nibe to dun mo mi ninu ni pe, lojo kan ni mo loo sise ni
Aloko-Ijesa, ibe ni mo ti koko ni anfaani lati lo si orileede Brazil lati loo
sere Sango, ti mo n yo ina lenu. Opo anfaani ni mo ti ri nidi ise yii, ati pe
opo oriire ti mo se lonii, nidi ise tiata yi naa ni.
AWIKONKO: Ina
ti e yo lenu, bawo lo se rorun si?
AJIKE: Ko rorun
looto, sugbon ise wa ni. Mo ti fi sile fawon to n bo leyin lati maa se e, bo
tile je pe mo si tun maa n se e leekookan. Lai pe yi ta a n se ayeye Sando-Ede,
mo lo sere nibe, mo tun yo ina lenu.
AWIKONKO: Se
ise yi ko di esin yin lowo sa, ati pe esin won le n se?
AJIKE: Esin
Kirisiteeni ni mo n se, ko si dii lowo. Oto ni esin, oto ni ise, ko si eyi to
di ekeji lowo, a ko gbodo je ki mejeeji papo mora won, nitori pe otooto ni.
AWIKONKO: Yato
si ere olofo, nje ipa min in tun wa te e le ko, ti e si maa se daadaa nibe?
AJIKE: Ko si ipa
naa ti mi o le ko nidi ise tiata, nitori pe Olorun lo fi ran mi. Bi mo se n baa
yin soro yi, o ti pe ti mo ti se ere olofo tipe. Eyi ti mi o le se ni ka maa
fenu ko ara wa lenu, nitori pe mi o nife sii. Ti won ba ni ki n se iya omo ti
ko gbonran, tabi eyi to gbonran, bo si je iya olowo ni, digbi ni mo duro lati
se e.
AWIKONKO: Ere
olofo ko fi bee wopo lasiko yi, ki lo fa a?
AJIKE: Ere olofo
ko tii pare, nitori pe Isese ko le pare lailai, ko si le parun.
AWIKONKO: Amonran
yin fawon to n se ere ifenukonu?
AJIKE: Ona ti
onikaluku gba wa sidi ise tiata, otooto ni, nnkan ta a si wa a ko nibe, ko papo
rara. Ipinu ta a ni wa sidi ise yi ko papo rara. Bi mo se wa yi, mo n dawon
eeyan lekoo nipa isese, eni ti ko si ba iyen wa ko le wo ibe. Amonran mi ti mo kan
le gba won ni pe ki won tete loo segbeyawo, ki won tete bi awon omo ti won ba
fe e bi kasiko too lo fun won. Bi e ba wo awon omo wa ta n gba lasiko yii, won
fe e sare tayo ni, obe to ti jinna ni won n wa kaakiri. Adura mi ni pe ki
Olorun tubo maa gbe ori gbogbo soke.