Gbogbo awon adije labe egbe oselu Alliance for Democracy (AD) nipinle Ogun ti leri pe awon ti setan lati gbakoso ijoba lowo egbe oselu APC lodun 2019.
Oluwaseyi Onifade Olowookere - Adije Sipo Gomina
Igbese lati de Oke-Mosan lojo kokandinlogbon osu karun un odun to n bo la ti n gbe yii, gbogbo awon omiran to n je gaba lowo bayii la maa gba akoso mo lowo lagbara Olorun.
Ko seni to le so pe igbaradi oun ti po ju, opo igbese la ti n gbe lati rii pe egbe oselu yi pa wa kale gege bi adije sugbon ti a ti pada ri ipo naa gba bayii, opo wa la si ti gbegba oroke pelu ogo Olorun.
A ti gbe ilana kale, a si ti gbaradi gidigidi fun idibo to n bo lona nii, bee la tun ti seto awon ona ta a fe e gba lati rii pe ipo gomina atawon ipo to ku ja mo wa lowo.
Gbogbo ijoba ibile kaakiri ipinle Ogun lati lo yato sawon ijoba ibile meji pere, latari awon idiwo kan si lo fa a taa ko tii se de be, sugbon lai pe, a maa debe, a tun si maa yika gbogbo awon ijoba ibile yi to fi mo awon woodu patapata.
A fe e rii daju pe a bawon eeyan wa soro, a si gbodo je ki won mo awon ipinu ta a ni fun won, leyin ta a ba mo awon ibi ti bata ti n ta won lese. Mo fe e je ki e mo pe lasiko yi, egbe oselu AD nikan ni egbe oselu to mo ona kan soso to fi le te awon eeyan lorun, nitori ta a mo awon nnkan ti won n fe e atawon nnkan ti won nilo.
Omo bibi ilu Oke-Ipaja niluu Ilaro ni mi, woodu kerin ni mo ti jade, ileese aladani ni mo ti jade, ti mo si fe e mu awon opolo ti mo ni lati wa a fi sin awon araalu, ki n si gbe ipinle Ogun laruge. Kii se pe mo kan fe e jade dupo lasan, mo fe e kopa to joju nigbesi aye awon eeyan ki n si sise de gbogbo agbegbe kaakiri.
Lara awon ise ti mo fe e se, eyi to je mi logun ju ni ti eto eko, ti mo si gbodo rii pe gbogbo awon eeyan ni je anfaani eto eko igbalode.
Kunle Babasanya Craig - Adije Sipo Omo-ile Igbimo Asoju-sofin niluu Abuja
Omo bibi Igbore niluu Abeokuta ni mi, mo fe e jade dupo omo ile igbimo asoju-sofin (House of Reps). Onimo-ero ni mi. Ko si nnkan meji to fe e je ki n jade dupo yi, bi ko se ti itara ti mo ni fawon eeyan nipa aseyori, to si maa n dun mi ninu lati rii pe awon eeyan gbe nnkan rere se.
Gbogbo eto lo ti pari lati rii pe a gba ijoba lowo awon to wa lowo won lonii. Inu mi kii dun bawon oloselu wa se n se ijoba, paapaa awon ta a yan lati loo soju wa, nitori pe gbogbo awon ileri won ni won ko mu se, to je pe nnkan ti won ko ran won lo se ni won n se.
KOMUREEDI NLEYE BOSUN - Adije Sipo Omo ile igbimo Asoju-sofin (House of Reps)
Omo agbegbe Ajebo nijoba ibile Obafemi Owode ni mi. Ipinu ti mo ni lati fe e jade dupo lati loo soju awon eeyan mi lagbegbe Obafemi Owode, Abeokuta North ati bee bee lo ni lati tun awon ipile to ti wo se (reposition), nitori pe opo awon nnkan ni ko lo bo se ye ko lo, idi ni pe opo awon ijoba ni won n fe e ya owo (loan), ti won si n fi owo yiya yi pon awon osise ijoba loju.
Nigba ti won ko ba san owo osu fun won lasiko, ipalara lo maa je fawon osise, dipo kijoba tun rawo ebe si won, se ni won a tun maa fiya je won, eyii ko si bojumu.
Ti e ba wo awon osise feyinti naa, ijoba n je won lowo osu odun merin, ti won ba tun fe e fun won, won ko tun ni fun won pe. Opolopo nnkan lo ti wo wa, ti a ko ba si tun un se, Naijiria ko le nilosiwaju.
Egbe oselu AD ni imo paapaa pelu bi iwe ofin wa tun se laa kale, atunto ati atunse lo je wa logun. Won fi aaye sile fawon oludibo lati se nnkan ti won fe. Egbe lo si n sakoso.
Odu ni mi, mi o kii saimo foloko, mo ti bawon eeyan mi soro, won si ti mo awon ipinu ti mo ni fun won, eyi to fi okan mi bale pe AD lo maa gbajoba lodun to m bo. A ni lati le egbe oselu APC danu patapata nitori pe oro won ti su araalu, won si ti de bebe tawon araalu yoo fi le won danu.
A ti mo awon ona ta a fe e gba lati rii pe gbogbo awon ipo wonyi ja mo wa lowo, nitori pe egbe oselu AD wa nikan lawon araalu gba pe o le yo ipinle yi kuro ninu oko iparun.
ABIMBOLA SAKA - Adije Sipo Omo ile igbimo Asoju-sofin lati ekun Ijebu
A ti gbaradi gidigidi, a si ti rii pe igbaradi wa n mu opin de ba awon nnkan tawon araalu n fe, fun idi eyi, mo n fi gbogbo enu so fun un yin pe opin ti de ba ijoba egbe oselu APC ati PDP nipinle Ogun.
Mo fe e fi da a yin loju, lati igba ta a ti n se ijoba awaarawa, ko tii si asoju gidi to ti mu ileri e se fawon araalu, etanje lo po ju lenu awon ti won ti loo soju awon eeyan won, ko si ye ko ri bee, fun idi eyi, awon araalu ti mo nnkan to to si won.
Ileri akoko ti mo fe e se fawon eeyan mi ni pe a maa soju won daadaa, ti a si maa rii daju pe won je mudun-mudun eto oselu awaarawa lodun to n bo. Mo si fe e gba won lamonran pe ki won foju sile daadaa lati ma tun se asise ti won ti se seyin.
KOMUREEDI OLUMIDE AWOLOWO - Adije Sipo Omo-ile igbimo Asofin lekun Guusu Abeokuta Akoko
Odu ni mi, mi o kii saimo foloko, mo fe e fi da yin loju pe lodun 2019, egbe oselu AD lo ni akoso ipinle Ogun. Ipinu ti egbe AD ni pelu iwe ofin wa, o fawon araalu lokan bale pe ko si iberu rara.
Bi e ba wo o ijoba gomina ipinle Ogun tele labe egbe oselu wa yi, Oloye Olusegun Osoba, iyen lodun 1999 si 2003, e maa rii pe ife araalu lo je wa logun, bee ba si wo awon ijoba AD kaakiri orileede yi, ko si awitunwi pe egbe yi mo nnkan tawon araalu n fe.
Fun idi eyi, mo gba awon araalu lamonran pe ki won ma siye meji, nitori pe ilana atawon agbekale ti won fi da AD sile si duro digbi.
No comments:
Post a Comment