Kani gbajumo oniroyin to tun je oludasile ileese Sahara Reporters, Omoyele Sowore mo pe awon kan ti n mura lati koju ija si niluu Ife ni, o see se ko ma pinu lati lo sibe lojo Tusde to koja yii.
Ohun ta a gbo ni pe bi okunrin to fe e jade dupo Aare orileede Naijiria lodun 2019, to tun feran lati soro abuku sawon agbaagba oselu to pe ni onijekuje se de Aafin Ooni Ife, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi ni won lawon to m duro de e ti bere sii fi ehunu won han.
Nigba ti won ni won rii pe okunrin naa ko fe e woju won lo mu ki won fin afefe tajutaju (teargas) sita, to si wo oju awon eeyan to tele Sowore atoun naa funra e lo.
AWIKONKO gbo pe lesekese lawon eeyan ti bere sii daku, awon meta la gbo pe daku, ki won too sare lo gbogbo agbara won lati da won pada saye.
Nigba to rii pe aarin ota loun wa, lo ma lo gbogbo ogbon lati salo kuro nibe, to si gba ori ero ayelujara twitter e lo lati loo ko o sibe pe die o ku ki won pa oun danu, sugbon ti Olorun ko won yo.
No comments:
Post a Comment