...Won loo fe e gbabodi fawon ni, kii se omo egbe won.
Titi di bi e ti n ka iroyin yi, iyalenu loro naa si n je fun opo awon omo egbe oselu APC nipinle Ogun, paapaa awon to gbo nipa bi won se yeye Seneto to n soju aarin gbungbun (Ogun Central) niluu Abuja, Lanre Tejuoso jade nibi ipade egbe oselu APC to waye niluu Abeokuta.
Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, ipade naa la gbo pe awon omo egbe oselu APC se fun ipalemo idibo abele egbe naa to n bo lona, ki won si forikori lori bi eto idibo naa yoo se lo nirowo-rose lai ni wahala kankan ninu.
Inu gbongan kan to wa nile ijoba ti MITROS, eyi to wa ninu Ibara Housing niluu Abeokuta la gbo pe ipade naa ti waye laaro yi, ko da a, to si n lo lowo titi ta a fi sakojopo iroyin yi tan.
AWIKONKO gbo pe nibi ti Gomina Ibikunle Amosun ti so ipinu e lati jade dupo Seneto labe egbe oselu naa lodun 2019, iyen leyin to ba gbe ipo gomina naa sile, to si tun je ko di mi mo nibe pe Ojobo, Tosde ola loun yoo fi oju eni toun fe e fa kale fun ipo gomina han fawon araalu, iyen nibi ipade tawon agbaagba naa koko se.
Won ni okan lara awon Oloye egbe naa lo daba pe ki won le Seneto Tejuoso jade sita nitori ti ko si ninu egbe won mo, to si see se ko gbabodi fun ipade tawon n se naa.
Fawon to ba mo bo se n lo nipa oselu orileede Naijiria daadaa, Seneto Lanre Tejuoso naa wa lara awon Seneto meedogun ti won fi egbe oselu APC sile lo si PDP, bo tile je pe lesekese loun naa ti sare soro pe oun ko si ninu egbe oselu kankan mo, to si je pe leyin e lo tun pada loo darapo mo won legbe APC.
Aba yi la gbo pe awon kan ti won ko gba ti Seneto naa faramo, ti inu won si n dun, sugbon ti won lawon kan an tako o aba naa pe omo egbe awon si ni Lanre Tejuoso.
Nibe loun naa ti je ko di mi mo pe aheso lasan ni iroyin naa pe oun kuro ninu egbe naa nitori pe kii se ona ti won fi n fegbe sile ni won loun fegbe oselu naa sile, ati pe lesekese loun ti pada nigba toun rii pe nise ni won fe e ba toun je nidi oselu.
Tejuoso gege ba a se gbo so pe oun fe e mo awon to wa nidi oro naa, keni naa wa a so o kan oun loju, nitori pe digbi loun si wa ninu egbe oselu APC, ti ko si seni to le le oun kuro nibe.
Nigba ti oro naa di ariwo, ti won lo so fe e di isu ata yanna-yanna, la gbo pe Gomina Ibikunle Amosun da sii, to si ni ki won pe Seneto Tejuoso pada lati wa a jokoo, ki won si jo sepade naa.
Sugbon a gbo pe lesekese ti won ni Tejuoso ti rii pe se lo dabi eni pe ipade ote ni won pe le oun lori, to si rii pe awon kan ti mura ote sile de oun, lo je ko fee binu lo kuro nibe, to si je pe se ni won pada be e pe ko jokoo pada.
Sa a, tawon ti ko ba mo, ipo Seneto ti Lanre Tejuoso fe e pada lo leekeji naa ni Gomina Ibikunle Amosun kede sita pnioun fee jade fun lodun 2019, ta a si mo pe nnkan ko le fara ro laarin Amosun ati Tejuoso funra e.