Idunnu ati
ayo lo ba de fun awon osise ijoba ipinle Osun ni bayii tijoba ti bere sisan
ekunrere owo osu kejo fun won pelu awon ajẹsilẹ ẹtọ won.
Yato si pe
won gba ekunrere owo osu kejo, ijoba san idaji-idaji ti owo won ti osu kesan,
ikewa, ikokanla ati ikejila ti odun 2015 seku fun won gege bii adehun to wa
laarin won.
Bee naa
nijoba san owo awon osisefeyinti fun awon osu ọhun, gbogbo owo to to si awon
osise fun isinmi won (leave bonus) fun odidi odun kan, iyen odun 2016 lo si di
sisan pelu.
Komisanna
feto isuna nipinle Osun, Bola Oyebamji lo salaye oro yii fawon oniroyin nilu
Osogbo. O ni imuse ileri yii ko seyin bijoba ipinle Osun se ri owo to le ni
bilioonu merindinlogun naira gba lara owo Paris Club latodo ijoba apapo.
O ni nigba
ti Gomina Aregbesola ba awon ti oro awon osise ijoba kan soro lori owo naa,
ijoba tun fi bilioonu meta kun owo naa, eleyii to so gbogbo re di bilioonu lona
ogun o din meji naira lati le fi derin peeke awon osise.
Oyebamji
salaye siwaju pe kii se igba akooko leyii tijoba yoo lo owo nla bee fun sisan
owo osu ati ajemonu awon osise, nitori adehun awon ni pe ni kete ti eto oro aje
ba ti gbenusoke lawon yoo bere sii san owo osu won lekunrere.
O ni dipo
kijoba da awon osise duro, okan pataki lara awon asiwaju awon osise, to loruko
rere, Alhaji Sunmonnu gba ijoba niyanju lati mu ona miin wo sisan owo osu.
Ijoba bere sisan owo osu lekunrere fun awon ipele kinni si ikeje,
idamarundinlogorin ninu ida ogorun fun awon ipele kejo si ikejila ati idaji fun
awon ipele iketala soke.
O so siwaju
pe odun 2014 ni eleyii bere titi di osu keje odun yii to dabi eni pe owo epo
tun gbenusoke die si loja agbaye.
Oyebamji waa
ro awon osise ijoba lati mase ya abaramoore jẹ, ki won te siwaju nipa sise
atileyin funjoba Gomina Aregbesola.