WASIU AYINDE YEYE AMBODE L’EKO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, September 18, 2018

WASIU AYINDE YEYE AMBODE L’EKO

AYEFELE OKEOWO

Gbogbo awon eeyan ti won saaba ma a n wa lori ero ayelujara ni won ti gbo orin kan ti gbajumo osere fuji nni, Alaaji Wasiu Ayinde ko, eyi to fi tabuku ba gomina Akinwunmi Amobde tipinle Eko.


Orin ohun ni K1 fi so fawon eeyan ipinle Eko pe ki won gbajoba kuro lowo Ambode, ki won gbe e fun Jide Sanwoolu ti Asiwaju Bola Ahmed Tinubu fa kale lati koju Ambode ninu abele egbe APC.

Orin naa lo ko bayii pe 'E gba  a lowo e, ko mo on lo, e gbe fun Jide, eni ba ju nilo, o le ju ni nu'. Orin yii lawon eeyan n ko kaakiri bayii.   

Fawon ti ko ba mo, ona to lagbara pupo ni wahala to n sele laarin asaaju egbe oselu APC lorile-ede yii, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ati gomina ipinle Eko, Ogbeni Akinwumi Ambode tun gba yo bayii.

Idi ni pe gbajugbaja osere fuji to wa lara awon to se ipolongo fun Ambode lodun 2015, Alaaji Wasiu Ayinde ti gbogbo aye mo si Oluaye Fuji ti so pe eyin Jide Sanwoolu ti Asiwaju fa kale lati dije ibo abele gomina ninu egbe APC loun wa bayii.

Ninu oro Wasiu Ayinde, ti won tun n pe ni Arabanbi lo ti so pe gbogbo aye lo mo pe ti Buhari, Osinbajo ati ti Sanwoolu loun se ni gbogbo ojo.

O ni gbogbo ohun ti Jagaban ba ti fe loun yoo ba fe. Orin to ko niyii, 'On your mandate, we shall stand, Bola, on your mandate, on your mandate, on your mandate, we shall stand'.

PÍN-IN KÁÀKIRI