Wahala De: Won Fe e Yo Ambode Gege Bi Gomina - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, September 12, 2018

Wahala De: Won Fe e Yo Ambode Gege Bi Gomina

Bi Gomina Akinwunmi Ambode tipinle Eko ko ba tete mura lati yanju wahala to wa laarin oun ati asiwaju egbe oselu APC lorileede Naijiria, iyen Oloye Bola Ahmed Tinubu, afaimo ni ki won ma yo o nipo naa lojiji ki saa isakoso e too tan.


B e o ba gbagbe, pelu bi nnkan se n lo bayii, aarin Gomina Ambode ati Asiwaju Bola Tinubu ko gun rege rara, ti Tinubu si n wa gbogbo ona lati yo o nipo, ko da a, to n leri pe oun ko nii je ki Ambode pada se ijoba eleekeji.

Gbogbo ona ti won ni Gomina Ambode n gba lati wa ojurere Asiwaju Tinubu pada lo n ja si pabo, pelu bo se n leri pe oun ko ni faaye gba Ambode mo ninu egbe oselu naa.

AWIKONKO gbo pe ojo keji ti Gomina Ambode loo gba tikeeti lati jade dupo gomina naa leekeji niluu Abuja, to si so o nita gbangba pe oun fe e pada sejoba leekeji ni won lawon ti n ko ara won jo lati yo Gomina Ambode nipo.

A gbo pe ipade ote lati yo Gomina Ambode naa ko seyin ti wahala to wa laarin oun Asiwaju Tinubu.

Won ni awon agbaagba, iyen awon alaga egbe naa lawon ijoba ibile ti ko din ni metadinlogota (57) ti won je omo eyin Tinubu ni won n sepade naa lati rii pe won dite yo Ambode danu.

Awon eeyan yi la gbo pe won ti fi erongba won han lati sagbateru eni ti Asiwaju Tinubu fe e fa kale lodun 2019, iyen Jide Sanwo-Olu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI