Olori ile igbimo asofin agba niluu Abuja, Seneto Bukola Saraki ti soro, o fowo soya pe oun setan lati gba ipinle Eko mo egbe oselu APC ti Oloye Bola Ahmed Tinubu je adari e lowo lodun 2019.
Seneto Bukola Saraki lo soro yi lojo Monde to koja yi lasiko to n bawon omo egbe oselu PDP soro, nibi abewo to loo se si won fun imurasile idibo abele to n bo lona.
O ni gbogbo agbara toun ni loun yoo lo lati rii pe egbe oselu PDP gba isakoso mo egbe oselu APC lowo, ati pe oun setan lati fa gomina kale fun ipinle Eko lodun 2019.
Saraki tun je ko di mi mo fawon omo egbe naa ti won lawon setan lati satileyin fun un pe oun yoo ri daju pe iya to ti n je egbe naa bo lati odun pipe wa, paapaa ipo ti won ti n jijakadi lati gba, sugbon to n bo mo won lowo loun yoo gba fun won lai ni wahala kankan ninu.
Ninu oro e, Seneto Saraki so pe "Nnkan ti e ti n jijakadi lati gba Layi opolopo odun seyin, e maa gba lasiko idibo to n bo lona yiyi nitori pe e ti ni enu kan to ni nnkan an se, to si ni gbogbo nnkan lati fiya je eni to ti n da yin laamu.
"Mo ni oogun to kapa eni to n pe ara e ni baba isale to n da awon araalu Eko laamu. A ni ise won lowo, lodun to n bo, PDP ni yoo gbajoba."
No comments:
Post a Comment