Segun Okewole
"E dana sun un, e ma je ko lo" lariwo tawon kan n pa nigba towo palaba gendekunrin kan ti won nise awon to n tun ero omi se, iyen plumber lo n se, eni ti won loo fipa bomodun mesan an sun, to si fa idi omo naa ya perepere.
Agbegbe kan ti won n pe ni Opolo niluu Yenagoa nipinle Bayelsa lo ti sele.
Ojo Tusde, ojo kerin osu yi la gbo pe awon obi omodebinrin odun mesan an naa ranse pe gendekunrin ta a ko tii moruko e titi ta a fi sakojopo iroyin yi tan pe ko wa a ba won tun ero omi won se ninu ile ti won n gbe.
Won ni gendekunrin to je omo bibi ipinle Rivers naa ko sese maa lo sile won, ko da a, ti won ni nibi ti aaye gba a de, ko sigba ti kii wole.
A gbo pe lojo naa, omodebinrin naa nikan lo wa nile, bo si se dele lo ti so fomo naa pe iya e lo ranse pe oun.
Nigba ti won loo beere pe talo wa nile, tomo naa si so pe oun nikan ni, lo je ko fogbon tan an baluwe tawon alejo maa n lo ninu ile naa, to si fipa bo pata, to bere sii ko ibasun fun karakara.
Ariwo ti won lopo naa n pa lo ta sawon araadugbo leti ti won fi wo inu ile naa lo, nigba ti won si maa ri gendekunrin yi, se lo n laagun bi eni to sese we tan, ti won si romo naa to n sunkun.
Idi niyii ti won lawon Fijilante agbegbe naa fi bere sii luu, tawon odo naa si bere sii lu bi eni maa ku, leyin naa la gbo pe won loo fa a le awon olopaa lowo.
No comments:
Post a Comment