Onarebu Bolanle Gbeleyi Gba Agbenuso Egbe Oselu APC Ni UK L'alejo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, September 3, 2018

Onarebu Bolanle Gbeleyi Gba Agbenuso Egbe Oselu APC Ni UK L'alejo

Ana ojo Sande, iyen ojo keji osu ta a wa yi, ni Onarebu Olusegun Bolanle Gbeleyi, to je okan lara awon oludije sipo asofin (seneto) niluu Abuja ninu idibo odun 2019 to n bo yi gba agbenuso egbe oselu APC ni United Kingdom, iyen Ogbeni Adewuyi Folarin Alao lalejo.


Gege ni a se gbo, abewo ti Ogbeni Adewuyi Folarin Alao se lo sile Onarebu Bolanle Gbeleyi ko seyin ona lati gbe oriyin ati osuba kare fun Gbeleyi pelu ipa ribiribi to ko lasiko iso-oru tawon omo egbe oselu naa se fun Aare Muhammadu Buhari fun ipalemo idibo to n no lona.

Nibi abewo naa la gbo pe okan lara awon agba oselu naa, iyen Adewuyi tun ti gba Onarebu Bolanle Gbeleyi lamonran fun ti ipalemo idibo abele, iyen primary to n bo lona, eyi ti yoo waye ninu osu yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI