OBASANJO KO LE DA ATIKU DURO LAILAI, KII SE OLORUN - TAHIR SHEHU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, September 23, 2018

OBASANJO KO LE DA ATIKU DURO LAILAI, KII SE OLORUN - TAHIR SHEHU

...O gbodo ranti igba Abacha

IGBAGBOYEMI ESUPOFO

Alaga egbe oselu PDP nipinle Adamawa, Alaaji Tahir Shehu ti so pe Aare teleri lorileede yi, Oloye Olusegun Obasanjo kere pupo lati da igbakeji Aare teleri lorileede yi, Alaaji Atiku Abubakar duro ninu idibo apapo odun to n bo lorileede Naijiria.


Shehu lo soro naa lai pe yi lasiko to n dahun ibeere nipa nnkan to ri si oro ti Oloye Obasanjo so pe Olorun ko nii dariji oun toun ba sagbateru Atiku lodun 2019.

O ni "Mo bowo fun Obasanjo to po gege bi Aare tele ri, olori orileede, agba oselu ati olori elesin, sugbon sibe, Obasanjo ko gbodo maa sebii pe oun ni Olorun, ko si gbodo gbagbe pe Olorun ni Olorun ise iyanu. Obasanjo je enikan soso to koko je igbadun ise iyanu Olorun ninu eto oselu to n lo yii.

"Mo fe ki Obasanjo ranti igba ti Abacha naa so pe oun ko nii darijin in, Abacha nigbabnaa so pe oun ko nii fi Obasanjo sile ninu ewon, sugbon se loun yoo pa a danu. O ti da ejo iku fun Obasanjo, o si n duro de ojo ti yoo fi onte lu idajo naa ki Olorun to o mu kuro, kii se pe Olorun mu kuro lori ite lasan, se lo tun mu kuro ninu aye. 

"Ojo ti Olorun mu Abacha kuro, ijoba ologuj nigba naa ti fowo si iwe pe dandan ni ki olori orileede orileede teleri, Jenera Abdulsalam Abubakar feyinti tipatipa. Abubakar lo gba ipo lowo Abacha, to si da Obasanjo sile kuro lewon.


"Olorun so pe Abdulsalam ko nii feyinti tipatipa, di po bee, lo pa Abacha to gbe Abdulsalam de ipo naa, to si yo Obasanjo kuro lewon, o seto idibo, o si gbe opa ase fun Obasanjo. Se Obasanjo ti gbagbe ife Olorun ni? Ta ni Obasanjo, to so pe oun ko nii dari ji Atiku. Ko gbodo gbagbe pe oun ko ni adari, Olorun Alagbara ni adari.

"Obasanjo gbodo ranti pe kii se oun lo gbe Atiku tabi eni to ba fe de ipo, Olorun nikan ni. Gege bi onimo nipa oro Olorun (theologian), Obasanjo gbodo mo pe boun ba ko lati dariji Atiku, ati pe to tun n leri pe boun ba si wa laye, Atiku ko nii di Aare, a je pe alawada lasan ni.

"Se o ti gbagbe ise Olorun ni, pe Olorun le sise iyanu to le yeye e danu, ko si je eni yepere. Adura mi si Obasanjo ni pe ko wa laaye; ko si wa nibe nigba ti won ba n bura fun Atiku gege bi Aare orileede Naijiria."

Bakan naa nigba to n gba Atiku Abubakar lamonran, Tahir Shehu so pe ki Atiku gboju kuro lodo Obasanjo, ko si ma feti si awon oro to n so, di po bee, ko tesiwaju lati maa sise to le gbe e wole gege bi Aare orileede yi, ati pe ko ma ronu pe Obasanjo lo le gbe oun debe, bi ko se Olorun to n funni lagbara.

O ni bi won ba n so nipa itan awon to ti gba orileede la, ko si bi won se maa so o, ti won ko nii daruko Atiku Abubakar, to si je pe Obasanjo gan an tun pelu awon to le jeri sii, ayafi to ba fe e paro.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI