IGBAGBOYEMI ESUPOFO
Bo tile je pe kii se akoko re e ti wahala yoo maa waye ninu egbe oselu alatako lorileede Naijiria, iyen Peoples Democratic Party (PDP), sugbon ona ti wahala tuntun yi tun gba yo lo n je kayeefi fawon omo egbe oselu naa, paapaa awon araalu to gbo nipa e.
Wahala naa be sile ni olu-ileese egbe oselu naa to wa niluu Abuja lojo Monde to koja yii, nibi ipade ti won se lati yan awon igbimo ti yoo sagbateru ipade gbogboogbo ti won fe e se lojo karun un ati ojo kefa osu kewaa to n bo yii.
Nibe ni awon oloye egbe naa tun koju ija sira won.
Ko si nnkan meji to ru wahala naa jade bi ko se ti ibi (venue) ti won fe e lo, bawon kan se faramo ilu Port Harcourt nipinle Rivers, bee lawon kan so pe ko te awon lorun, tawon ko si nii gba.
AWIKONKO gbo pe igbimo ti won gbe dide fun ipade gbogboogbo naa, ti Ambasado Ibrahim Kazure je alaga fun ni won so pe ipinle Rivers ni won fenuko si pe ki won lo, sugbon tawon kan so pe awon ko nii gba ko waye nipinle naa.
Won ni bi won ba gbe ipade gbogboogbo naa lo sipinle Rivers, gomina ipinle naa, Nyesom Wine yoo lo anfaani naa lati polongo ibo fun okan lara awon adije sipo Aare orileede yi toun gba tie, to si see se ko sakoba fawon adije to ku.
Fawon to ba mo bi nnkan se n lo daadaa legbe oselu PDP, paapaa nipa ti idibo Aare to m bo lodun 2019, won yoo mo pe adije metala lo fe e jade dupo kan soso naa legbe PDP, tonikaluku won si n wa ona bi won yoo ti jawe olubori nibi idibo abele to fe e waye.
Nigba to n soro, igbakeji alaga egbe oselu naa lapapo (South), Ogbeni Taiwo Akinwomi so pe egbe naa ti fenu ko si pe kawon lo Port Harcourt, iyen ipinle Rivers nitori pe ibi ti alaga igbimo ti won yan naa fowo si niyen, ko si ye ki oro naa di wahala.
Iyalenu lo je pe Akinwomi ko tii soro naa de le ti alaga igbimo agba (BoT) fi pa oro naa mo lenu, pe ko ye e so isokuso nitori pe ko seni to fenuko pe ki won lo ibi kan, ati pe awon si n jiroro lori e lowo ni.
No comments:
Post a Comment