Bo tile je meji pere lawon emi to sofo danu nibi ikolu ti won lawon adigunjale ti loo kolu awon osise ile itura De Queens to wa lagbegbe Ekpena Road, nijoba ibile Ahoada East Local Government, ipinle Rivers.
Ale ana, Fraide la gbo pe awon adigunjale naa ya wo oteeli naa, ti won si dabon bole lesekese ti won bo sile ninu moto won.
Bi won se n yinbon naa kaakiri lo ti loo bawon eeyan, tawon meji si ku lesekese, tawon min in naa si farapa yanna-yanna.
Leyin isele naa la gbo pe won gbe awon to farapa lo si osibitu fun itoju, ti won lawon olopaa si gbe oku awon to padanu emi won lo si mosuari.
Iwadii awon olopaa ti bere gege ba a se gbo.
Lara awon to farapa nibi isele naa le n wo foto e loke yii.
No comments:
Post a Comment