Bi iroyin to te AWIKONKO lowo lai pe yi ba fi le je otito nipa wahala ti won lawon omo egbe oselu African Democratic Congress, iyen ADC n fojoojumo fa n'Imeko Afon nitori adije sipo gomina ipinle Ogun lodun 2019, Omoba Gboyega Nasiru Isiaka (GNI), a je pe a fi ki okunrin naa to ti du ipo kan soso leemeji otooto, sugbon to n ba ijakule pade tete mura, ko si pe awon omo eyin e naa lati ma ba oruko e je.
O
hun ta a mo daju ni pe, okunrin naa, iyen GNI ko mo nipa nnkan to sele yii, ko si le se iru nnkan to jo be e, nitori pe ojurere awon araalu lo n wa, ti ko si nii fe kawon omo eyin ti won ko mo nnkankan ta abuku ba oruko e.
Gege bi isele se s'oju AWIKONKO, ojo Monde onii lawon omo egbe oselu ADP nipinle Ogun ti Oloye Adewale Egunleti je alaga won pinu lati loo fi ile egbe naa lele, ki won si tun yan awon oloye ti yoo sise fun egbe naa, iyen nijoba ibile Imeko-Afon.
Eyi lo fa a ti won lawon omo egbe oselu ADP nijoba ibile naa ti Onarebu Adewole Peter Akanni je alaga won fi bere ipalemo eto naa, ko le dun, ko si larinrin.
AWIKONKO gbo pe laaro kutu ojo Monde naa, tii se onii ojo keta osu kesan an lawon omo egbe naa loo sare bere sii le awon alemole (Postal) egbe naa lati le je kawon ara agbegbe naa mo nnkan ti won fe e se, ati lati dari awon alejo to n bo wa si gbagede ti eto naa ti fe e waye.
Lara awon to firoyin isele naa to AWIKONKO leti je ko di mi mo pe ko tii ju wakati kan ti won le awon alemole (postal) egbe oselu naa mo awon agbegbe kan ta a gbo pe awon toogi kan loo bere sii fa a ya.
Ninu iwadii la ti gbo pe awon omo eyin Omoba Gboyega Nasiru Isiaka ni won wa nidi e, nitori ta a gbo pe gbogbo ona ni won n wa lati ma je ki egbe oselu kankan yato si egbe oselu ADC ti GNI fe e gba jade lodun 2019 duro nile Yewa, paapaa nijoba ibile Imeko-Afon to ti wa.
Won ni bawon omo egbe oselu ADP se rii pe won ti n fa awon alemole naa ya danu ni won tun pada loo le awon alemole min in mo awon ibi ti won ti fa a ya, sugbon ko ju iseju meedogun lo ta a tun gbo pe awon toogi kan tun loo fa a ya.
Bee ni won tun so pe nigba tawon omo egbe oselu ADP tun de awon agbegbe kan, se ni won ba awon toogi naa ti won n fa awon alemole naa lowo.
Ohun ta a gbo pe o je iyalenu ni pe kaka kawon omo egbe oselu ADP naa so oro naa dija, se ni won tun petu sawon toogi naa ninu pe ki won gba alaafia laaye, sugbon ti won lawon toogi naa yari mo won lowo.
Bo tile je pe saaju akoko yi niroyin ti kan kaakiri pe awon kan n gbaradi lati da eto ti egbe naa fe se ru, ki won si lu awon agbaagba egbe naa to ba yoju nilukulu, ti won ko si ji faaye gba won.
Bi iroyin naa se te alaga egbe naa nijoba ibile Imeko-Afon lowo loun naa ti sare bere igbese lati wa bi wahala ko se nii sele, to mu ki okunrin Onarebu naa gba tesan olopaa lo lati loo fi to won leti nibe.
AWIKONKO tun gbo pe se ni alaga naa, Onarebu Adewole Peter Akanni pe ipade alaafia laarin awon oloye gbogbo egbe oselu to wa nijoba ibile naa, nibe ni won ti je ko ye ara won pe oselu kii se nnkan ti won le pa ara won le lori.
Siwaju sii la tun gbo pe bawon agbaagba egbe oselu ADP nipinle Ogun se de si gbagede ti won ti n seto naa ni won lawon kan sare loo pade won, ti won si ri awon kan to dori awon alemole naa kodo fi ki awon oloye naa.
Eyi gan an lo je kawon ti won ko mo nnkan to n lo fura pe nnkan ko fara ro niluu naa, sugbon ti won lawon omo egbe oselu ADP ko woju won, kaka ko won woju won, se ni won tun fi ayo pade won.
Lati fidi iroyin naa mule, nigba to n b'AWIKONKO soro, Onarebu Peter Akanni so pe looto ni, sugbon toun ko setan lati daruko egbe oselu to wa nidi iwa naa, nitori toun mo pe awon ti oye ko ye nidi oselu ni won n hu iwa adojutini naa, lati fi ba oruko egbe oselu won si ni.
Onarebu naa to loun ti figba kan ri gbe apoti, toun si wole lai ti e le alemole (postal) kaakiri nigba naa tenumo on pe ko digba teeyan ba le alemole naa kawon eeyan to o le gba ti e, nitori pe ise to ba se sile, tabi bo ba se lokiki to ni yoo je kawon eeyan dibo yan an.
Akanni je ko di mi mo pe egbe oselu ADP ko si fun wahala, tawon ko si ba enikeni figagbaga, idi ni yii toun fi loo foro naa to gbogbo ileese eleto aabo bii olopaa, sifu difensi, to fi mo Fijilante atawon min in leti ki won le wa a daabo bo won nibi eto naa.
Bee lo kadi oro e nile pe oun tun ti sepade papo pelu awon oloye egbe gbogbo egbe oselu to wa nijoba ibile naa, ti gbogbo won si gba lati gba alaafia laaye.
Bakan naa, akowe egbe oselu nijoba ibile naa, Komureedi Olojede Sarafadeen naa fidi e mule f'AWIKONKO, O loun tun koja lawon agbegbe kan tawon le alemole naa si, toun si bawon toogi naa nibe.
O loun mo won daadaa nitori pe awon jo wa niluu ni, sugbon tawon ko si fun wahala, to mu kawon gbe awon igbese alaafia tawon gbe, toun si mo pe ko nii si wahala mo.
Siwaju si lati fidi e mule, AWIKONKO gbiyanju lati bawon oloye egbe oselu ADC nijoba ibile naa soro, sugbon gbogbo akitiyan lati ba won soro lo ja pabo titi ta a fi sakojopo iroyin yi tan.
Iyalenu lo je pe se lawon toogi da wahala nla sile bo se ku die ki won pari eto naa, ti won bere ija nla gidi, ija naa la gbo pe o tu eto naa ka.
Awon to b'AWIKONKO soro so pe awon toogi naa kii se omo bibi Imeko-Afon, won ni agbegbe Obada nitosi Imeko ni awon to wa a da wahala naa sile ti wa.
No comments:
Post a Comment