Oludije fun ipo gomina, Seneto Iyiola Omisore
labe asia egbe oselu SDP ninu ibo to waye nipinle Osun ni Satide, ojo Abameta
to koja yii ti di ojulowo oloselu bayii ti gbogbo awon oloselu egbe e n wa
kiri.
Bi awon egbe oselu APC se n wa okunrin
oloselu yii, to ti figba kan se igbakeji gomina ri, bee lawon PDP paapaa ko je
ko gbadun niseju kan, nise lawon egbe mejeeji yii n be e gidigidi, ti won si n
fi orisirisi ipo be e paapaa.
Ohun kan pataki ti won n be Omisore fun ni bi
yoo se darapo mo won, ti atundi ibo to fe waye ni Tosde to n bo yii, yoo
senuure fun won.
Okan lara awon oloselu to sepade pelu Seneto
ohun loni-in ni Aare ile igbimo asofin Seneto Bukola Saraki. Ninu oro ti Bukola
Saraki so fawon oniroyin ni kete to kuro lodo Omisore ni pe, “Ipade to so eso
rere la jo se pelu Seneto Omisore, bee la nigbagbo wi pe awa egbe oselu PDP la
o jawe olubori. Ipade ohun si n te siwaju, nitori a tun n bo lola, a si
nigbagbo pe yoo yori si rere fun egbe wa.”
Iyiola Omisore ninu oro tie naa so pe, loooto
lawon egbe oselu mejeeji, APC ati PDP ti n wa oun kiri bayii, bakan naa lo fi
kun un pe, egbe oselu SDP toun dije loruko e setan lati sise papo pelu eyikeyi
to ba setan lati tele akosile erongba rere ti egbe naa ni fun araalu.
Te o ba gbagbe, ninu ibo to waye lojo Satide,
egbe oselu PDP ti Ademola Adeleke dije loruko e lo n le iwaju pelu ibo egberun
lona igba-o-le-erinle-laaodota ati ibo mokandin-leedegbinrin (254,699), nigba
ti Isiaka Oyetola toun dije labe asia egbe
oselu APC ni tie ni ibo egberun lona igba-o-le-erin-le-laaodota ati ibo
oodunrun-o-le-marun-un-din-laadota (254,345).
Seneto Iyiola Omisore, to dije loruko egbe
oselu SDP, to siketa ninu idije ohun pelu ibo egberun lona
eji-din-ni-aadoje-o-le-mokandinlaadota (128,049).
Ni bayii ti ajo INEC ti kede wi pe atundi ibo
yoo waye lojo Tosde to n bo ni awon agbegbe yii, Orolu, Osogbo ati Ife, gbogbo
ona lawon oloselu mejeeji yii, APC ati PDP n wa lati fi fa oju Omisore mora, ki
ibo e le kun tiwon, ki won baa le jawe olubori ninu atundi ibo naa.
Lati: OJUTOLE-TOKO