NITORI AMBODE: AWON ARA EPE FI AROKO IKU RANSE SI WASIU AYINDE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, September 26, 2018

NITORI AMBODE: AWON ARA EPE FI AROKO IKU RANSE SI WASIU AYINDE

Ona to lagbara pupo bayii ni yeye ti gbajugbaja osere fuji nni, Alaaji Wasiu Ayinde fi gomina ipinle Eko, Ogbeni Akinwumi Ambode se lori ero ayelujara gba yo bayii.


Ohun ti Ojutole gbo ni pe awon ara Epe ti Ambode ti  wa so pe awon ko gbodo ri gbajumo osere fuji naa nilu awon mo, won ni to ba se e si wa si Epe, ko ni i faraare lo.

Nibi ti oro yii bi awon eeyan yii ninu de, won tun leri pe awon ko ni i gbese orin fun K1 mo, gbogbo ona lawon yoo si gba lati ri i pe awon ore awon paapaa koyin si osere omo bibi ilu Ijedu-Ode yii.

Ohun tawon eeyan yii so ni pe ohun ti Wasiu Ayinde se yii, ki i se Ambode nikan lo kan labuku,gbogbo ara Epe ni,nitori pe asoju awon gidi l'Ambode n se.

Ju gbogbo e lo, awon ara Epe n binu si Oluaye awon onifuji, won si ti leri pe awon yoo ba a mu nnkan nile to ba wa siluu awon.    

Lati: OJUTOLE-TOKO

PÍN-IN KÁÀKIRI