Onarebu Adekunle Adeyemi to ti figba kan ri je omo ile igbimo asoju-sofin, to soju ekun Ifo, Ewekoro niluu Abuja ti so pe oun setan lati tesiwaju nibi toun ba ise de lakooko toun fi wa nipo naa laarin odun 2011 sodun 2015 iyen ti won ba foun ni tiketi lati dije labe egbe oselu APC.
O soro yii lakooko to n fara e kale fawon omo egbe naa, eyi to waye niluu Ifo. O so pe inu oun yoo dun bi won ba le fimosokan foun ni tikeeti naa fun ibo to n lodun 2019. O salaye pe boun ko se jawe olubori nibi ibo odun 2015 nigba toun fee lo eleekeji ko je abamo foun, bee se lo tun faaye ope sile ni.
Adeyemi tun salaye pe ki i soro enu, oun mo pe oun sa agbara oun lati mu iderun ati igbe aye alaafia wa fawon toun soju ati pe opo awon eeyan lo ti pase rise labe ijoba apapo, bakan naa lo tun so awon ise akanse mi in tun ti wa nile ti won ba foun ni tikeeti naa.
O tun so pe oun naa mo pe pelu atileyin awon eeyan naa loun se de ipo naa nigba naa ati pe igi kan ko le dagbo se, nitori e loun tun se n ro awon omo egbe oselu APC to wa ni Ifo lati tun se iru ifee bee lati fi gbe oun wole.
Ati pe ki i se nitori ara oun loun se fee lo si Abuja bi ko se lati soju won lohun,kawon anfaani to ba to si won ko le maa kan won loorekoore. O ni ki won je ki ala toun la si Ifo, Ewekoro lati di ohun nla, ti oro aje yoo si maa lo deede di mimuse.
Leyin to soro tan, ni lara awon oloye egbe naa ni Ifo naa kan jeri sii pe o se iwon to le se nigba to fi wa nibe ati alaaanu eeyan,won si ro awon yooku lati fowosowopo lati je ki won fun un ni tiketi lati le se awon nnkan to wa lokan e to ba de be, beeni won tun so awon nnkan ti won fee ko se fawon, toun naa si seleri pe oun yoo se e.
No comments:
Post a Comment