...Mi o se ojo ibi fun iyawo mi ri - Wolii Alayo
Ojo ibi je ojo ayeye ti eeyan gbodo maa se e, paapaa bawon iwe mimo naa tun se fidi e mule. Idi ni yii to fi je pe beeyan ba n sayeye ojo ibi, o gbodo maa ranti awon ojo adojuko ti yoo fi maa dupe lowo Olorun Olodumare fun aabo emi, ipamo ati alaafia to n fi fun ni.
Okan lara awon iyawo iranse Olorun toun naa tun je iranse Olorun ti Olorun n gba owo won sise ara, aami ati ise iyanu, Wolii-binrin Hannah Idowu Adebayo topo awon eeyan mo si Mama Alayo ti so nipa ojo ti inu e baje ju nile aye, si iyalenu, ayajo ojo naa tun bo si asiko ojo ibi e.
Mama Alayo lo soro nipa ojo naa lasiko to n b'AWIKONKO soro nipa die ninu irin ajo aye e nibi ayeye ayajo ojo ibi aadota to se niluu Abeokuta lojo Wesde to koja yi, ko too gba ise iranse Olorun, ati leyin to gba ise iranse naa tan. Bo se so nipa ojo ibanuje naa, lo tun so ojo ti inu e dun ju laye.
Yato si Mama Alayo to soro, oko e, Wolii Alaba Timothy Adebayo tawon eeyan tun n pe ni Baba Alayo naa so die nipa iwa iyawo e, ko da a, to tun je ko di mi mo pe akoko re e toun yoo sayeye ojo ibi fun un lati bii odun mejidinlogun tawon ti jo wa gege bi oko atiyawo.
E ka bi iforowero naa se lo, pelu ohun tawon eeyan tun so nipa Mama Alayo:
Oruko mi ni Wolii-binrin Hannah Idowu Adebayo ti opo awon eeyan mo si Mama Alayo
Die nipa irin ajo aye mi
Oluwaseun, lati ibere pepe aye mi, bo tile je pe idile o nigbagbo ni mo ti jade, omo iranse Olorun si ni mi peluu, mo si ti m sise fun Oluwa ni mo ti n sise fun Olorun ki n to o pade oko mi. Ki n to o pade oko mi, mo maa n so pe mi o le fe iranse Olorun, ko da a, ti mo tun maa n fi adura tii leyin tori pe bi mo se gbe lodo iranse Olorun, mo maa n ri awon adojuko tawon obinrin maa n ba pade, eyi lo mu mi pinu pe mi o le fe iranse Olorun, lai mo pe riro ni teniyan. Nigba ti mo pade oko mi, ise telo (tailor) ti mo ko loun naa n se, eyi lo mu ki inu mi dun pupo pe mo ti ri eni ti mo fe e fi se Ade ori lai mo pe Olorun fi bo mi loju ni. Ninu irin ajo ibanidore wa ni mo rii pe oko mi tun n gbadura fawon onobaara e, aya mi tun bere sii ja pe iranse Olorun ni mo tun pada pade.
Nigba to ya orisirisi isele aburu bere sii sele, ofiisi ti won n lo wo lule lojiji, won ti ko ile epo sibe bayii, igba to ya, a tun ri ibomin, ko pe ni gbogbo awon omose wa tun kuro. Igba yen lawon eeyan, to fi mo awon iranse Olorun ti won bere sii pe mi lati maa so fun mi pe Olorun fe e lo emi ati oko mi, a si gbodo jowo ara wa sile fun un. Laarin irin ajo yen naa lemi ati omo mi nijamba moto, to je pe Olorun lo ko wa yo, nigba to ya, mi o ni nnkan min in lati se mo ju pe ki n gba kadara mi lo, ti mo si gba fun Olorun lati lo mi. Mo beere lowo Olorun boya lotito ni Olorun fe e lo emi ati oko mi, pe ko fi aami otito naa han, ko pe ni lanloodu fun wa niwe pe ka keru wa jade, osu meta ni lanloodu fun wa nitori pe kootu lo gbe wa lo. Iyalenu lo je pe laarin ose meta pere, Olorun ko ile fun wa, igba yen ni mo fi ara mi sile fun Olorun lati lo.
Inu ile naa la ti bere ijosin, igba to ya, a lo m ya aga kaakiri, igba to tun ya to di pe inu ile ko gba wa mo, a loo se atibaba siwaju ita, ko to o di pe Olorun gbe aanu e dide, ti a si ti fe e ko soosi naa pari bayii.
Iha tawon eeyan ko si mi nigba ti mo gba ise Olorun
Looto, awon ore mi sa fun mi, ti won lawon ko le ba mi se mo. Won n so nigba naa pe pelu hi mo se rewa to, se o ye ko je pe iranse Olorun ni mo maa fe, won n so pe se ni oko mi maa bo irawo mi mole, mi o ni le mura bo se ye. Orisirisi oro ni won so, sugbon igba ti mo rii pe esu lo fe e lo won fun mi, mo tete kuro lodo won lati koju mo ise ti mo gba. Inu awon ebi mi dun, paapaa awon egbon mi nitori pe iranse Olorun lawon naa fe, paapaa bo tun se je pe inu idile iranse Olorun la ti jade. Mama mi so fun mi pe awon ti maa n riran si mi pe iranse Olorun ni mi lati kekere.
Ojo ti inu mi baje ju
Ojo kefa osu kesan an, odun 2003 lojo ti mi o le gbagbe laye mi. Ijamba moto ni mo nigba naa, emi ati omo mi keji la jo wa ninu moto lojo naa. Mo n bo lati ayeye ipade awon odo (Youth Conference) kan ni lona Arakeji, emi ati omo mi keji, Ireoluwa Adebayo la jo lo. Igba ti a n bo la ni ijamba naa, to je pe osu meta la lo ni osibitu nigba naa ni UCH, Ibadan. Eemeta otooto ni won sise abe (operation) fun mi. Mi o ranti ayajo ojo omi to je ojo ibi mi nigba naa, ori beedi osibitu naa ni mo wa, ti mi o le dide, mi o le gbe apa ati ese mi, oju kan ni mo wa fun odiidi ojo mejidinlogun (18days), ore mi kan, Oyeyemi toun naa je iyawo iranse Olorun lo loo ta ebun wa fun mi, igba ti mo taji ni mo ri ebun naa, oun lo ran mi leti pe ojo naa ni ayeye ojo ibi mi, se ni mo bu sekun, ko pe ni oko mi naa tun gbe ebun tie naa de, tawon min in naa tun gbe ebun wa fun mi. Ojo naa ba mi ninu je nitori ipo to ti ba mi nigba naa, sugbon mo gbe oruko Olorun ga lonii pe gbogbo e ti di eri (testimony) bayii.
Ojo ti inu mi dun ju
Ojo onii, ojo kejila osu kesan an odun 2018 ni inu mi dun ju, mo fe e le so pe lati ojo Monde ni mi o ti sun. Ohun ti mi o lero pe o le sele lo sele si mi lonii nigba ti awon eeyan rogba yi mi ka. Mi o lero pe awon olorin emi ti ni o mo ri le wa lati wa a korin fun mi. Iru e ko sele ri laye mi.
Bi ayeye ojo ibi yi se ri lara mi
Ojo onii je ojo to lagbara ninu aye mi nitori pe mi o tii se iru ayeye bayii ri, osu yi tun je osu ti opolopo ijamba buburu ti sele si mi ri, sugbon ti Olorun ko mi yo ninu re. Bi wahala naa ti po to, Olorun gba gbogbo ogo lori aye mi.
Amoran mi fawon iyawo iranse Olorun, paapaa awon to n bo leyin
Amoran mi si gbogbo obinrin lagbaye ni pe ki won ni suuru, ipamora ati ifarada, tori pe igbeyawo je ohun to lagbara pupo ti ba gbe ti ise iranse segbe kan. Igbeyawo je adojuko ti ko seni to le mo nnkan ti yoo sele nibe. O digba to ba wonu e tan, ko too le bere sii ri awon adojuko naa. Ojo airije, ojo airimu, ojo ailowo lowo ati bee bee lo. Opo igba la ti mu gaari, igba min in wa to je pe aawe ati adura la fi gbe e, to je pe nigba to ya, se ni mo bere sii ni aarun jejere (ulcer), sugbon ni bayii, itan ni.
Ohun ti mo ri nipa orileede Naijiria
Emi gbagbo nipa Olorun ti mo n sin pe ko si nnkan ti ko le se. Ojo iwaju rere wa fun Naijiria, nitori pe ilu Beulah, ti Olorun ni. Mi o tii ri ipejopo iranse Olorun ti won ko gbadura fun orileede Naijiria. Ninu iran ti mo n ri, okan mi bale pe Naijiria si maa dara, mo si fi n da gbogbo eeyan lojo pe Olorun wa lorileede yi, ojo iwaju rere si wa fun wa.
OHUN TAWON EEYAN SO NIPA MAMA ALAYO
Mi o sayeye ojo ibi fun iyawo mi ri - Wolii Alaba Timothy Adebayo to je oko Mama Alayo
Nnkan ti mo koko ri nipa iyawo mi ni pe, o ni ifarada pupo, o si korira iyanje, kii fe e se nnkan to maa ba mi ninu je, kii se nnkan to maa ni mi lara, kii beere nnkan ti agbara mi ko ba ka. Nitori e ni ife yen tun se n jinle lokan mi. Bi e ba se nnkan kekere fun iyawo mi, se lo maa gbe e bii pe o ju bee lo ni. Odun yi lo pe odun mejidinlogun (18years) ta a ti fera, mi o se ayeye ojo ibi fun un ri, akoko re e. Mi o ti e tii se bayii, nitori pe ibi yi ko gba wa, ati pe gbogbo eto ti a ti la kale, agbara ko gbe, nitori e ni mo se sun un siwaju di ojo min in.
Eni iyi ni iyawo mi. Mi o rii gege bi iyawo mi, bii iya ni mo se rii ninu igbesi aye mi. Ki a to o fe ara sile niyawo mi ti n ba mi fo aso. Iyawo mi kii fi nnkan pamo fun mi, ko da a, ti m ba nilo iranlowo owo, o tun maa fun mi ni. O si tun nife awon omo e, atawon eeyan gidi. Ko si nnkan ti mi o le se fun iyawo mi. Mi o ra moto fun iyawo mi ri, bo tile je pe mo ti fawon eeyan ni moto bii mefa daadaa, sugbon lai pe yi ni enikan wa a fun mi ni moto tuntun, lesekese loju gbogbo eeyan ni mo ti fa kokoro moto naa le e lowo nitori pe moto naa po ju mi lo. Iyawo mi ju bee lo. Mo fe e gba gbogbo eeyan nimonran pe bi won ba fe e yan ololufe e won, ore won ni ki won fe, ki won fe oluranlowo won, ki won ma fe aninilara won. Won ko gbodo je eni to n ni ara won lara, won si gbodo mo eni ti won ba fe e fe daadaa.
Arabinrin Yussuf Oluwatoyin Makinde
Bo tile je pe odun 2016 ni mo mo won, sugbon mama mi ni won je nitori pe mi o le ka iyen nnkan ti won ti se fun mi ri tan. Ki n to o se igbeyawo ni won ti n toju mi, ko da a, awon ni won gbe bukata to po ju lori ayeye igbeyawo mi. Awon to bi mi gan an ti yonda mi fun won. Emi ni won maa n pe ni akobi won nitori owo ti won fi mu mi. Beeyan ba nisoro, to ba lo k ba won, se ni won maa gbe e sori bii pe awon ni. Awon ti ko mo wa papo tele, bi won ba ri bi a se jo n se e, won maa ro pe awon ni won bi mi ni. Ti m ba ni ogbe okan, awon ni mo maa n koko pe. Mi o le gbagbe won laye mi.
Alufa Ojetola Christopher Adedamola
O maa to o pe ogbon odun ti mo ti mo Mama Alayo, mi o kii se ajoji si idile won. Bi won ba n so nipa idile to se e mu yangan ninu igbagbo, akoko ni won je. Pelu gbogbo adojuko oun ati oko e, sibe, o duro sinsin pelu ife e. Inu mi si dun si awon mejeeji daadaa nitori pe eeyan daadaa ni won je.
Pasito Samson
O ti fe e pe odun mewaa bayii ti monti mo won. Mama je akikanju obinrin teeyan gbodo maa toro iru eeyan bii ti e lowo Olorun, nitori pe obinrin to ni ifarada ati ifayaran ni, Olorun si fun won ni aseyori ninu irin ajo ise iranse won, eni to tun gbaruku ti ipe oko e daadaa ni. Obinrin to se e fi yangan ni
Pasito Ogundeyi Oluwatoyin
Gege bi obinrin Olorun, won gbagbo ninu Jesu pupo, won tun ko awon eeyan mora, ise iranse won naa tun tu awon eeyan lara. Amonran mi fun won ni pe pelu bi won se ko awon eeyan mora to, ki won tubo se bee maa jinle si ninu ise Olorun, ki won ma fa seyin. Olorun a si tubo maa daabo bo awon ati idile won.
Diakoni Oluwole Olujoke Olaitan
Odun merin seyin ni mo ti mo won. Nnkan ti mo le so nipa won ni pe won je eeyan kan to maa n fi inu tan awon eeyan, won si loyaya pupo. Mi o figba kan ri won nibi ti won ti n binu ri, looto won le maa binu o, sugbon mi o ri won bee ri. Olorun n lo Mama yi fun Ayo daadaa, kii sii foju pa eeyan re. O tun maa n gbadura gidigidi. Mo gbadura pe ayo naa ko nii kuro ninu aye won pelu oruko won.
Leyin awon obi mi, idile Wolii Adebayo ni mo tun mo l'obi - Olumide Awolowo
Ti m ba ni ki n maa so oro naa lati oni di odun to n bo, mi o le so o tan nitori pe ipa ti won ti ko nigbesi aye mi ko kere rara. Latigba ti mo ti mo won, se ni won mu mi bi omo, won kii fe ki iya je mi, adura ni won ma n gba fun mi ni gbogbo igba ti a ba n soro. Iru eeyan bii ti Mama Alayo sowon laarin awon obinrin. Mi o mo bi o ba se dupe, sugbon mo nigbagbo ati idaniloju pe Olorun a ba mi san won lesan rere. Yato si pe won n gbadura fun mi, won tun maa n gba mi lamonran bi aye mi se maa ni itesiwaju.
Bakan naa la tun gbo pe ana naa ni ojo ayajo Ogbeni Kabir Lawal topo awon eeyan tun mo si LawestLawest, eni ti won loun ni akowe ori oke adura Alayo, ti won si jo o ge akara oyinbo papa lojo naanaa lati fi saami ayeye ojo ibi won.
No comments:
Post a Comment