LOOTO NI WAHALA WA NINU EGBE OSELU APC NIPINLE OGUN O - AKOWE IJOBA PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 13, 2018

LOOTO NI WAHALA WA NINU EGBE OSELU APC NIPINLE OGUN O - AKOWE IJOBA PARIWO SITA

...sugbon a ti n yanju e - Adeoluwa

Akowe ijoba ipinle Ogun, Barisita Taiwo Adeoluwa ti soro, o fidi e mule pe looto ni wahala nla wa ninu egbe oselu APC nipinle naa, ti kii sii se aheso tabi iro rara.


Irole ojo Wesde to koja yi ni Barisita Taiwo Adeoluwa to tun je agbenuso fun Gomina Ibikunle Amosun soro naa lakoko to n bawon oniroyin ipinle Ogun soro lori awon awuyewuye to n lo ninu egbe naa.

Lojo Tusde ose yii ni wahala nla kan sele ni gbagede Presidential Lodge, nibi ti Gomina Amosun pe awon oloye ati omo egbe oselu APC nipinle Ogun jo si lati le yan awon ti yoo dije sawon ipo nipinle ati niluu Abuja lodun 2019, eyi ti won pe ni Consensus candidates.

Ija la gbo pe won fi tuka lojo naa, paapaa nigba ti won tun so pe awon kan ti won je omo egbe Komisana foro odo ati ere idaraya, Onarebu Afolabi Afuape bere sii gbe gomina Amosun sepe lori ona to gbe yiyan awon adije sipo naa gba.

Bo tile je pe lati ojo Monde ti won ti bere eto naa lawon eeyan ti n fehunu han pe igbese ti gomina Amosun gbe naa ko te won lorun, sugbon ti won gba kadara pe bi Olorun se ko ti won niyen.

Sugbon saa, se loro yi pada lojo Tusde nigba ti won ni won tun yan awon ti yoo dije lati loo soju nile igbimo asofin agba ati asoju-sofin niluu Abuja lodun 2019 ko te won lorun, pelu bi won se yo oruko awon kan kuro, ti won si fi tara won sii.

Idi ni yii ta a gbo pe awon omo egbe oselu naa se yari pe nnkan to ba gba lawon maa fun un, paapaa bi won tun se so pe awon merin ti won je molebi gomina Amosun lo wa ninu awon ti won yan, ti won si tun yo oruko awon molebi agbaagba egbe oselu naa kuro, eyi ti won ni ko dun mo awon omo egbe naa ninu.

Boro naa se di isu ata yanna-yanna ni yii, paapaa nigba ti won tun yo oruko Onarebu Afolabi Afuape kuro ninu awon ti yoo lo soju awon eeyan niluu Abuja kuro ninu awon oruko ti won ko sita.

AWIKONKO gbo pe se lawon alatileyin okunrin naa, Afuape to je Komisana foro awon odo ati ere idaraya se bere sii se epe rabande-rabande fun gomina Amosun ni yii pe awon ko nii ko ibi ti oro naa yoo ja si.

Bi eyi se n lo lowo ni won lawon kan toro naa soju won bere sii fi foonu won ka isele naa sile, ti won si pada gbe fidio bi gbogbo nnkan naa se sele sori ero ayelujara lati mo iya ti Gomina Amosun fi n je awon omo egbe oselu APC nipinle Ogun.

Bo tile je pe AWIKONKO pada gbo pe awon oloye egbe naa lapapo niluu Abuja ti fa iwe oruko awon oludije ti won ko ranse naa ya pe egbe ko fowo sii pe ki won se konsensoosi (consensus), pamari (primary) ni won fowo si, paapaa bi won tun se n fiya je awon omo egbe naa lona aito.

Idi ni yii ti Barisita Taiwo Adeoluwa to je akowe ijoba ipinle Ogun pelu Onarebu Afuape atawon min in fi sare pe awon oniroyin die lati mu ori won mo abe pe ki won bawon tun iroyin naa ko sita pe ko si nnkan to jo o pe awon kan n bu gomina Amosun.

Si iyalenu e, gbogbo awon oniroyin ipinle naa ni won lo lati loo gbo nnkan to fe e so, toun naa si fidi e mule pe oun ko ranse pe gbogbo won, awon die lasan loun kan fe e ba soro.

Nigba to si n soro, Adeoluwa so pe "Mi o lero pe e le po to eyii, se lo ye ki n maa beere idi ti e se po bayiibayii, bo ya e tun fe e gbo nipa iroyin yajoyajo (breaking news) ni. Akoko re e ti maa ri awon oniroyin to po bayii. O tun mo si pe nnkan to n lo ninu egbe oselu wa a le fe e mo. Sugbon sibe, mo ni iroyin ayo fun un yin.

"Adari wa lati ijoba ibile Abeokuta South wa nibi, gbogbo yin le mon on. Won ti pe akiyesi wa si iroyin kan ti won ko ko daadaa, to si n lo kaakiri nipa eto to waye nirole ana (Tuesday evening). Mo ti pe ore mi yi (Afolabi Afuape), o si ti soro, iyalenu lo si je pe iru nnkan bee sele.

"Looto ni mi o si nibe, Afuape funra e naa ko si nibe, sugbon pelu esi abajade ti a ri gba lati odo akowe egbe wa nipinle Ogun, pelu awon agbaagba egbe oselu wa, o yato patapata si nnkan ti eyin oniroyin ko pe o sele.

"Mo fe e mu da a yin loju pe ninu egbe oselu APC nipinle Ogun, paapaa nijoba ibile Abeokuta South ti emi ti wa, okan soso ti a ko pinya ni wa, enikeni ko si le ri aarin wa, nitori pe a duro sinsin ni. Ojogbon ni opo ninu yin nidi ise yii. E si mo pe niru awon asiko bayii, iru awon nnkan to n sele yi ko maa n saba sele iru.

"Sugbon sa, ebi kan soso ni wa, ti a si ni ona ti a n gba lati yanju awon isoro wa. E jowo, e ba wa so fun won nita pe nnkan ti won gbe jade nipa isele to sele lana ko ri bee, asise lasan ni. Opo ninu yin le gbe oro si Onarebu Afuape lenu pelu nnkan ti ko so.

"Nitori pe adari wa (Afuape) ko si nile, igba to si de, o wa a ba mi, o si fidi e mule fun mi pe nnkan ti won ko naa kii se otito nnkan to sele. A ni isoro ti wa bi awon to ku naa se ni ti won, mo si fe e fi da a yin loju pe gbogbo awon isoro wa lati ti n gbe igbese lati yanju won."

Bo tile je pe Adeoluwa to je akowe ijoba ko soro nipa nnkan ti won ko naa, eyi lo fa a ti die lara awon akoroyin naa fi beere lowo e pe soju abe nikoo, ko si iru iroyin naa sita lati le fidi e mule.

O ni "Won so pe nigba ti won n seto lati yan awon adije konsensoosi (consensus) naa, won ni Onarebu Afuape fi ibinu ati ibanuje okan kuro nibe nitori pe won ko muu. Ko ri bee, looto ni mi o si nibe, sugbon gege bi molebi kan soso ti a je, a ni ona ti a n gba lati yanju aawo (issues) to ba wa laarin wa. A si ti n sise lori e.

"E pada loo so fun won pe ninu egbe oselu APC nipinle Ogun, paapaa ninu isejoba wa ti emi je akowe ijoba, ati paapaa nijoba ibile Abeokuta South ti mo je okan lara awon agba nibe, okan soso ni wa. Looto ni wahala wa sugbon a ti n gbe igbese lati yanju e. E se pupo."


Onarebu Afolabi Afuape
Mo ro pe nnkan ti e n se ko le salai ma ri bee. E kan n gbiyanju lati fe e mo nnkan to sele nibe ni. Looto mi o si nibe, sugbon awon alatileyin mi wa nibe. O see se ki wahala wa nibe nitori pe a ni awon to nigbagbo ninu wa gidigidi. Sugbon sibe, egbe wa, egbe isokan ti molebi kan soso ni, nitori pe gbogbo wa n sise lati mura sile de idibo apapo odun 2019 to n bo lona si ni, a si gbodo je eyokan soso.

Ko si egbe oselu ti ko ni isoro ti e, ko si si isejoba to lo geerege lai ni konun-koho ninu nile aye yii. Mo n so fun yin pe awon alatileyin mi wa nibi eto naa, emi si ni won n soju nibe, nitori pe adari won ni mo je, mo fi n da a yin loju pe ko seni to bu gomina Amosun. Mo so fun un yin pe mi o si nibe, mo si nigbagbo pe bi mo ba wa nibe, gbogbo nnkan to sele yen ko le sele bee.

Ko si wahala pe won n bu gomina Amosun rara, nitori pe adari wa ni gomina je. Nnkan to ba mu ki won bu gomina, o ti je pe emi gan an ni won n bu niyen. Mo nigbagbo ninu awon alatileyin mi pe won ko le wo ara won nile debi pe won yoo bu gomina tabi awon adari to n tuko egbe oselu wa nipinle wa.

Mi o le so fun un yin pe ko si oruko mi ninu awon oruko ti won ko ranse, mo ye awon oruko naa wo, ko si si oruko ti won da nijoba ibile Abeokuta south, a ti n wa ona lati yanju wahala to wa ninu egbe wa. Ko si nnkan ti ko le sele, bi oruko mi ko ba si ninu awon oruko ti won ko, o si le pada jade ninu awon oruko min in.

Eyii to se pataki ni pe ki gbogbo wa fi idunnu han si bi eto naa se n lo sii, ti mo si fi da a yin loju pe inu mi dun si. Oselu ti wa la n se yii, e fi wa sile ka se e funra wa, ko kan enikeni

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI