AYEFELE OKEOWO
Okan lara awon omo Oloogbe Moshood Kasimawo Olawale Abiola, Ogbeni AbdulMumuni Abiola ti so pe kii se iru asiko bayii ni odo lawon fe e de ipo Aare lorileede Naijiria, nitori pe ko tii to asiko.
Ana tii se ojo Abameta, iyen Satide ni AbdulMumuni Abiola fi erongba e han nibi ayeye apapo awon odo, iyen National Youth Summit, akoko iru e ti egbe odo kan nipinle Kwara ti won pe oruko won ni Zealous Kwara Youth niluu Ilorin sagbateru e.
Ninu oro e, o so pe "Mo gbagbo pe asiko kan n bo, gege bo se wa lorileede Canada ati France, ti a maa ni enikan tojo ori e ko tii ju ogbon odun lo nijoba.
"Mi o ro pe asiko naa ti to bayii. Mo lero pe o nidii kan ni pato ti Aare Buhari fi wa nibe, ma a si fe ka ni suuru pelu e. E je ka fun un lanfaani odun merin in min in, ti mo si nigbagbo pe odo ni yoo gbe ijoba fun un.
"Mi o ni eni ti mo tun fe e se ipolongo ibo fun ju eni to wo sunsun leyin ogun odun, to si bu ola fun baba mi, eyi tawon to ku ko se. Idi ni yii, Buhari lemi fe e tele lodun 2019 lati pada leekeji."
No comments:
Post a Comment