AYEFELE OKEOWO
Oniroyin kan, Ogbeni Yomi Obaditan ti so pe oludije funpo gomina ipinle Osun labe egbe oselu APC, Alhaji Isiaka Gboyega Oyetola nikan lo kunju osunwon laarin awon ti won jade lati dupo naa.
Obaditan ni ohun meji otooto lo mu ki eto idibo gomina ipinle Osun ti odun yii yato si eyi ti won ti n se tele. Akooko ni bi awon oludije mejidinlaaadota se jade lati gbapo lowo Aregbesola, eekeji si ni pe gbangba lo rorun fun awon araalu lati mo eni to ni okan lati sin awon araalu ati eni to kan jade laini afojusun kankan.
O ni ise gomina kii se fun eni ti ko ni imo kikun nipa isejoba, o je eyi to nilo olopolo pipe, to ni ogbon atinuda lati mu ki aye ro awon araalu lorun, gbogbo amuye yii lo ni o wa lara Alhaji Oyetola gege bii eni to ti sise aladani fun o le ni ogbon odun ko too di pe o di olori osise loofiisi gomina.
Obaditan fi kun oro re pe eni ti yoo se gomina laseyori gbodo mo pe eto aabo ẹmi ati dukia awon eeyan ipinle oun se pataki, sugbon ti awon araalu ba ti le se asise yiyan eni ti ko le danuro, tabi ti ko le da duro lori ẹsẹ araa rẹ, o di dandan ki wahala wa ninu isejoba bee.
Gege bo se wi, "Ti a ba n soro nipa iriri; yala lenu ise aladani tabi ti oselu, okan soso ajanaku ni Gboyega Oyetola, yato si pe o lanfaani lati ba gomina to se daadaa julo lorileede yii sise, o tun wa lara awon ti won tun itan Osun ko nipase ise ribiribi tijoba Aregbesola se laarin odun mejo isejoba re.
"Ti a ba n so nipa eto eko, eni to kawe gboye lorileede yii ati loke okun ni Oyetola, eleyii si fun un lanfaani lati se ejika aagbẹru si fun imuse awon koko elega mefa tisejoba Aregbesola duro le, paapaa, aseyori to ba eto ipese ise fawon odo, iyen O'YES ti banki agbaye gan an ti so pe awokose rere ni fawon gomina ti won ba feran awon odo ipinle won.
"Ko si eni to le ba Aregbesola sise fodun mejo ti ko nii ri eko rere ko lara re, Oyetola si safihan eleyii lasiko eto iforojomitooro oro tileese telifisan Channels sagbekale re, o dahun gbogbo ibeere pelu ogbon to tayo ti awon to ku, bee lo han kedere pe o mura sile fun ise naa.
"Fun odun mejo to fi sise pelu Gomina Aregbesola, ko seni to ri ariwisi kankan si i pe boya o ko owo jẹ tabi pe o se owo ilu basubasu, eleyii tun fidi re mule pe eni to kunju osunwon fun ise naa ni, idi si niyii ti iwe iroyin Guardian se fun un lami eye gege bii olori osise loofisi gomina to pegede julo lorileede Naijiria nibere odun yii.
"O ni akoyawo, bee lo ko gbogbo eeyan mora. O ti seleri lati lo iriri re nipa eto okoowo lati le mu ki owo to n wole labenu nipinle Osun gbenusoke sii. Awon eeyan Osun ko gbodo faaye gba enikeni lati da Isreali won pada si Egypti, itesiwaju gbodo ba awon ise akanse meremere tijoba to n kogba wọle yii n se lowo".
Obaditan, ninu iwoye re, so pe ẹkun aaringbungbun Osun ti Oyetola ti wa lo ni iye oludibo to po julo nipinle Osun, o si se e se ki eleyii sise fun un nitori awon eeyan ti setan lati san esan ise rere tijoba Gomina Aregbesola ti se l'Osun fun un nipase idibo gomina to n bo yii.
No comments:
Post a Comment