Aare Muhammadu Buhari ti gboriyin fun Minisita foro eto isuna owo, Arabinrin Kemi Adeosun lori igbese to gbe nipa bo se kowe fipo e sile lonii.
Ninu atejade ti agbenuso Aare, Ogbeni Femi Adesina fi sita lo ti fidi e mule, to si tun ti dupe lowo e fun ipa to ko lasiko to fi sise, bee lo gbadura fun un.
Latigba ti iroyin ti jade sita pe Minisita foro eto isuna owo lorileede yii, Arabinrin Kemi Adeosun ti kowe fipo e sile, tawon eeyan ko si tii le fidi e mule daadaa, boya looto ni tabi iro ni.
Bawon kan se n ki obinrin naa fun igbese akikanju naa, bee lawon kan n bu enu ate lu esun ti won fi kan an, toun naa ko si tii soro nipa latigba naa.
Fawon to ba mo bi nnkan se n lo, nipa oro Kemi Adeosun, ko si nnkan meji ti won loo mu ko kowe fipo sile bi ko se ti esun ti won fi kan an pe o se ayederu iwe eri agunbaniro, eyi to fi n sise bayii.
AWIKONKO gbo pe bi Kemi Adeosun se de ofiisi e laaro onii, ko ba enikeni soro rara to fi wonu yara ofiisi ti e gangan, ko si pe e ta a gbo pe o fi fibinu jade sita pada.
Ohun to je kawon eeyan maa so pe obinrin to wa lati ipinle Ogun naa kowe fipo sile ni ti leta ti won ri lowo e, to si ni aami idanimo (Letterhead) orileede yi ninu.
A gbo pe se ni obinrin naa tun palemo die lara awon eru e to wa ni ofiisi e, to si ko o sinu moto, idi ni yii ti won fi bere sii gbe e kaakiri pe Adeosun ti kowe fipo e sile, bo tile je pe ko tii seni to le so igba ti yoo dawo ise naa duro.
Eto agunbaniro tawon akekoo jade maa n lo fun, eyi ti won ni Kemi Adeosun ko ba won kopa ninu e ri lorileede Naijiria ni won so pe o loo se ayederu iwe eri e.
Bo tile je pe ko seni to tete fura nipa iwe eri naa, sugbon nigba ti awon ayewo kan n lo lasiri too tu sita pe inu osu kesan an odun 2009 ni won bu owo lu iwe eri naa, to si je pe eni ti won loo bu owo lu iwe eri naa, iyen Jenera Yusuf Bomoi, inu osu kinni in odun naa lo feyinti.
AWIKONKO gbo pe ni nnkan bi aago mejila osan onii, won si ri Kemi Adeosun ninu ofiisi e, to n sise lowo, ko da a, awon moto e tijoba gbe lee lowo naa si wa nibe, tawon osise naa wa lori iduro.
Lara awon alabasise po e to ba okan lara awon akoroyin soro ni nnkan bii aago merin irole onii, eni naa to ni ka foruko boun lasiri so pe Kemi Adeosun ko tii kowe fipo sile, ati pe to ba je bee, ijoba apapo yoo gbe atejade sita lati fidi e mule.
Sugbon atejade ti Ogbeni Femi Adesina fi sita yi lo fidi e mule daadaa pe ijoba apapo ti gba a wole.
Bee la tun gbo pe Aare Muhammadu Buhari tun ti pase pe ki Arabinrin Zainab Ahmed to je Minisita foro ilana bi a se n seto isuna (Minister of State Budget and National Planning) bere ise ti Kemi Adeosun fi sile naa.