AYEFELE OKEOWO
Olopaa kan toruko e n je Folake Ogunbodede, to n sise ni tesan olopaa Ipaja, niluu Eko lawon agbofinro n wa bayii lori esun pe o gun oko e, Taiwo lobe, nitori ede aiyede to sele laarin won.
Gege bi Ojutole se gbo, aaro ojo Abameta, Satide to koja ni ija kekere kan sele laarin won, ti Taiwo si fi ile sile funyawo e olopaa ti won pe ni sajenti yii.
Nitori bi Taiwo se sa kuro nile fun iyawo e yii lo se so fun un pe oun ko gbodo ri i ko pada wa sile mo, sugbon ale ojo naa lokunrin ti won gun lobe yii pada wa sile, pelu erongba pe inu iyawo oun yoo ti ro, sugbon ohun ti ko ro lokan lo ba pade, nibi to to jokoo si lobinrin olopaa yii ti gun un lobe, ti Taiwo si subu lule.
Bi Folake se ri i pe oun ti daran lo sa lo, awon ara adugbo ni won gbe Taiwo lo sile iwosan nibi to ti n gbatoju lowo bayii.
Tuesday, September 18, 2018
KAYEEFI: OLOPAA GUN OKO RE PA L'EKO
Tags
# KAYEEFI
PIN-IN KAAKIRI
NIPA IROYIN AWIKONKO
KAYEEFI
Tags:
KAYEEFI
PÍN-IN KÁÀKIRI
Author Details
Ile-iṣẹ AWIKONKO MEDIA CHANNEL lo n gbe IROYIN AWIKONKO jade pẹlu ontẹ Ijọba orilẹ-ede Naijiria labẹ ajọ iforukọsilẹ nni, iyẹn CORPORATE AFFAIRS COMMISSION. A fẹ ki ẹyin ti ẹ n ka Iroyin Awikonko mọ daju pe a ko ni i gba ẹnikẹni laaye lati ṣe ẹda iroyin wa, tabi gbe e jade ninu iwe iroyin min in lai gba aṣẹ lọwọ awọn alaṣẹ wa, ẹsẹ ofin la o fi gbe onitọhun. Bẹẹ, a ko ni fẹ ki ẹnikẹni ṣi iroyin wa ka, nitori pe iwadii kikun la n ṣe ka to le gbe iroyin jade, nitori naa, bi ẹ ba ka ifọrọwerọ pẹlu eeyan, ohun ti ẹni naa ba sọ, ki i ṣe awa la sọ ọ, ẹni naa lo sọ bẹẹ. Fun alaye lẹkunrẹrẹ, tabi ipolowo ọja yin, ẹ le kan si wa lori: +2347012342712.