KAYEEFI: OGA ILEEWE GIRAMA LE AWON AKEKOO MUSULUMI DANU L'EKO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 20, 2018

KAYEEFI: OGA ILEEWE GIRAMA LE AWON AKEKOO MUSULUMI DANU L'EKO

Opo awon to gbo nipa bi oga ileewe girama kan niluu Eko, iyen Isolo Senior Secondary School se le awon akekoo-binrin marun un kan danu lojo Wesde to koja yi ni won bu enu ate lu iwa naa.


Gege bi AWIKONKO se gbo, kii se pe oga ileewe naa ti won pe oruko e Arabinrin J.O Sadare dee de le awon akekoo naa danu, sugbon nitori Ijaabu tawon obinrin elesin Musulumi maa n lo, eyi ti won lawon omo naa lo lojo naa lo se le won pada sile won.

AWIKONKO gbo pe ori ila, lasiko tawon akekoo gbogbo wa nileewe l'oga ileewe yii kede pe oun ti le awon omoleewe naa danu, ki won pada si ile awon obi won.


Be o ba gbagbe, lodun to koja ni wahala wiwo ijaabu lo sileewe di wahala lorileede Naijiria, bawon kan se faramo, bee lawon kan ko gba ti e, paapaa bijoba tun se so pe awon yoo so o di ofin.

Awon to firoyin isele naa to AWIKONKO leti je ko di mi mo pe awon akekoo yii ti won je musulumi ko lo sile won, dipo bee Keke Napep kan to wa nitosi ileewe won ni won so di yara ikawee, ibe ni won ti kawee won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI