Okan
lara awon oludije sipo omo ile igbimo asoju-sofin kekere niluu Abuja,
House of Reps lodun 2019, Ogbeni Ayodeji Michael Shomide ti je ko di mi
mo pe ipinu rere ati idagbasoke alailegbe toun ni fawon ara agbegbe oun
yato si tawon asiwaju ti won ti se tele atawon to n se lowo, lo je koun
fe e lo soju won niluu Abuja ninu idibo to n bo lona..
Shomide
to je omo bibi Ago-Oba niluu Abeokuta soro naa lai pe yi, iyen lose to
koja lasiko to n b'AWIKONKO soro nile egbe oselu APC to wa ni
Abeokuta South, iyen Okejigbo, Abeokuta, lasiko to loo farahan awon
oloye egbe naa ti Alaaji Lateef Adenekan je alaga fun.
Gbajumo
onisowo naa so pe bo tile je pe asiko ipolongo idibo ko tii de, sibe
oun ko gbodo salai ma tete wa a farahan fawon oloye egbe toun fe e gba
jade. Bee lo seleri pe oun setan lati fowosowopo pelu won, koun si maa
tele amoran ati ase ti won ba pa foun.
Bakan
naa lo tun je ko di mi mo pe igba akoko re e toun yoo wonu oselu, toun
si mo pe pelu awon iriri toun ni lorileede Naijiria ati loke okun toun
ti kawe yoo je koun se daadaa, paapaa bo se je pe asiko awon odo lati
gbajoba la wa yii.
O
wa a fi kun un idi ti ko tii se si idagbasoke daadaa ni bi awon olidibo
ko tii se yan olooto bii toun sipo, toun si mo pe oun ko nii dale won.
Nigba
to n soro, alaga ijoba ibile naa, Alaaji Lateef Adenekan so pe bo tile
awon nigbagbo ninu Shomide nitori tawon mo on daadaa, sibe oun ko le
salai ma gba nimonran pe ko mura daadaa, nitori tawon to fe e jade dupo
naa si n bo, paapaa tawon min in ti wa a ba won lori ipo kan soso naa.