Ohun ta a
gbo ni pe lojo Satide ose to koja yi la gbo pe awon obi odomobinrin eni odun
marundinlogbon (25) kan, Idowu Ogunkoya sakiyesi pe omo won n hu awon iwa kan
ti ko ye enikeni, ti won lo si jo bi eni pe awon aje n ba finra.
Idi ni yii
ti won ni won fi gbe Idowu lo sile Lekan ti won nise babalawo, iyen Ayelala lo
n se lati ba on toju e, ko le gbadun ladugbo Ojuolota, opopona Ijesha niluu
Ago-Iwoye.
Nigba ti
won de be, ti won ni won salaye ohun toju won n ri nipa awon iwa kayeefi ti Idowu
n hu gege b'AWIKONKO se gbo, won ni etutu ni Lekan so fun won pe oun yoo
se fun Idowu ko to o le gbadun, iyen leyin igba ti won loo ti d'ifa lati mo
nnkan to n sele.
A gbo pe
bawon obi Idowu se gba pe ki etutu naa bere kawon ma ba a foju sunkun omo losan
ganagan lo mu ki Lekan pase pe ki won gbe e wonu igbale (shrine) lo, ki etutu
naa le bere.
Won ni
lesekese ni Lekan ti fa irun ori Idowu lati sin gbere (incision) sii, sugbon to
koko fun un ni agbo mu. A gbo naa la gbo le Idowu n mu lowo to fi subu lule, to
si bere sii pofolo.
Ere ni won
koko pe e, to mu ki won maa ro omi le e lori, ti won ni Lekan naa sare bere sii
pogede lati je ki ara e wale, sugbon lojiji ni won so pe Idowu dake mon on
lowo.
Iroyin iku
Idowu lo te oko afesona e, Lucky Oghenetega lowo lojo Sande ose to koja yii, to
fi gba tesan olopaa Ago-Iwoye lo lati loo fesun kan Lekan nibe, tawon olopaa
naa si loo muu ninu igbale to sapamo sii, iyen ba a se gbo.
Bo tile je
pe ohun tawon eeyan n so ni pe elegbe ni Idowu, to si je pe asiko to da fun won
ninu egbe lo pe, ti won fi wa a muu lo, sibe, nnkan kan soso to ti e tun n ya
awon eeyan to gbo sisele naa lenu ni bi won se ni Lucky tun fesun kan baba
Idowu, Ogbeni Temitayo Ogunkoya pe oun naa lowo ninu iku omo e to je iyawo
afesona oun, to si ni kawon olopaa ko awon mejeeji.
Esun ta a
gbo pe Lucky fi kan won ni pe kaka ki won gbe Idowu lo si osibitu nibi ti won
yoo ti toju e, ti yoo si tete gbadun, se ji won gbe e lo sodo babalawo.
Oro naa la
gbo pe won n fa titi to fi ta si Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu leti lojo
Tosde, to si pase pe ki won maa gbe Lekan bo wa si Eleweran, nibi ti iwadi yoo
ti bere ni pereu.
Nigba to n
fidi isele naa mule, Alukoro fawon olopaa ipinle Ogun, DSP Abimbola Oyeyemi bu
enu ate lu iwa naa, to si ni oga awon ti pase pe ki eka ileese won to m ri si
iwa odaran abele, Homicide tesiwaju ninu iwadii.
Bee lo so
pe oga won ti gbawon araalu lamonran pe ki won yago fun awon iwa asekupani naa,
paapaa eyi to ba ti je mo itoju emi.