AYEFELE OKEOWO
Ajo to n sakoso eto idibo nipinle Osun, INEC ti kede sita pe awon ti fagile idibo to waye lawon agbegbe meta otooto nipinle Osun latari awon awuruju to sele nibe lopin ose to koja yi.
Ajo INEC so pe se ni won yoo tun ibo naa di lojo Tosde to n bo yi, iyen ojo ketadinlogbon osu yii. Awon agbegbe naa ni ijoba ibile Ife South, Ife North ati Orolu, nibi ti won ni madaru lorisirisi ti waye.
Adari ti won lo fun akoso eto idibo naa, Ojogbon Joseph Fuwape to je giwa fasiti ilu Akura, FUTA lo kede sita fawon araalu pe awon ko nii le tesiwaju eto idibo naa, ayafi tawon ba tun ibo naa di.
Fawon to ba n tele bi idibo naa se n lo, won yoo mo pe awon adije meji ni won n jawe olubori ninu eto idibo to n lo lowo yi, awon naa ni Seneto Ademola Adeleke ti egbe oselu PDP ati Ogbeni Gboyega Oyetola ti egbe oselu APC.
AWIKONKO gbo pe die pere ni Seneto Adeleke ti egbe oselu PDP fi n la akegbe e legbe oselu APC, iyen Oyetola.
Ibo 254,698 ni ajo INEC kede pe Adeleke fi n lewaju Oyetola toun ni ibo 254,345.
Bo tile je pe saaju akoko yi ni Seneto Adeleke ti pariwo sita pe ki ajo INEC seto naa bo ti to ati bo ti ye, ki won ma si se madaru lati yi ibo naa fun akegbe e legbe oselu APC.
AWIKONKO gbo pe lara awon awuruju ti won loo sele lojo Satide ana ni won ti so pe awon kan ji apoti ibo gbe salo, ti won si lawon ti kaadi idibo alalope, PVC won ko sise naa tun idibo atawon orisirisi esun min in ti won fi kan awon agbegbe meteeta naa.
Bakan naa la tun gbo pe ibo 3,498 ni ibo ti danu, ti ajo INEC si ti leri pe afi ki won tun ibo naa di, ki won too gbe abajade esi naa jade.