Kaayefi loro iku Refurendi kan ti won poruko e ni Jude Egbuom si n je fawon eeyan to gbo nipa e, paapaa awon omo soosi e pelu bi won se so pe awon adigunjale ni won seku pa a.
Ref Fr Jude Egbuom ni adari soosi Aguda, iyen Catholic eka ti St Patrick to wa niluu Nkwerre, ijoba ibile Njaba nipinle Imo. Ale ojo Monde to koja yi la gbo pe awon adigunjale naa loo dena de lasiko to n lo sile e, ti won si pa a danu, bee ni won tun gbe moto ayokele to n lo salo.
AWIKONKO tun gbo pe yato si Refuendi ti won pa yii, awon adigunjale naa tun yinbon pa okunrin kan ta a ko tii moruko e dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan, eni naa la gbo pe o wa ninu moto pelu e lasiko ti won n sise ibi won lowo.
Awon to gbe iroyin naa si wa leti je ko ye wa pe irun ni Redurendi naa loo ge lagbegbe Anara-Nkwerre Road ni ale ojo naa, nnkan bi aago mejo to n pada sile e ni won da a lona.
Won ni kii se pe won dee de yinbon pa a, sugbon nigba ti ko tete fi kokoro moto e ti won n beere lowo e sile, to tun fe maa ba won sagidi lo mu ki won yinbon fun un pelu eni to jokoo legbe e, ti won si wo awon mejeeji bo sile, ki won to o gbe moto naa salo.
AWIKONKO gbo pe awon olopaa ti bere ise iwadii won.