Inu idunnu ati ayo nla ni gbogbo awon omo orileede Naijiria wa titi di bi e ti n ka iroyin yi pelu bi gbajumo afeseku-bi-ojo nii, Anthony Joshua se fi agba han akegbe e, Alexander Povetkin nibi idije ta lo lagbara ju, eyi to waye lojo Satide to koja yi.
Bo tile je pe nigba ti won koko bere ija naa, ni Anthony Joshua ti n padanu merin si meji 4-2 si owo Povetkin, sugbon nigba to ya, ni Joshua loun ko nii gba, a fi koun rii daju pe oun gbegba oroke.
Povetkin la gbo pe latigba to ti n ja, to si n gba aami eye, ko tii seni to fidi e jale ri, to si ti gba opolopo goolu nibi idije kaakiri agbaye, pelu awon afojusun to ma fi n ja awon ija e.
Sugbon se loro naa yi pada ni ale ana nigba ti Joshua fidi e jale nibi ija onipele meje (7rounds) naa.
Ni bayii, o ti di ija mejilelogun (22) ti Joshua ti ja lai kuna nibi kankan, to si je ko je eni to mon on ja ju lagbaye.
Nigba to soro nipa ija tawon eeyan ti ko din ni egberun lona ogorin (80,000) lo o wo, Joshua so pe oun ti maa n so fun ara oun pe looto ni Povetkin ti gba aami eye goolu lopo igba, to si ti ja gba oye agbaye (world title), sugbon nigba toun ti de, o ni lati teriba.
Joshua tun so pe o ye ki won gbe iroyin fun Povetkin pelu awon iriri e to n ja, ati pe oun farapa gidi, nitori pe idije naa ko rorun, sugbon toun ni lati fara da a.
No comments:
Post a Comment