EMI O FI EGBE OSELU APC SILE O - ALAO AKALA PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, September 11, 2018

EMI O FI EGBE OSELU APC SILE O - ALAO AKALA PARIWO SITA

Gomina teleri nipinle Oyo, Adebayo Alao-Akala ti pariwo sita pe awon to fe e ba toun je ninu egbe oselu APC ni won n so pe oun gbero lati fi egbe naa sile lati loo darapo mo egbe oselu min in.


Be o ba gbagbe, ana tii se Monde ni Alao-Akala gba ilu Abuja lo lati loo fun egbe oselu APC lapapo ni foomu to gba lati jade dupo gomina naa loduj 2019.

O ni aheso ti ko lese nile ni won n gbe kaakiri pe oun fe e fi egbe naa sile lati loo darapo mo egbe min in ki ipinu oun lati tun jade dupo gomina toun ti gbe sile lati bii odun meje seyin le wa si imuse.

AWIKONKO gbo pe leyin awon ipade ti Gomina ipinle naa, Abiola Ajimobi se pelu awon to fe e jade dupo naa, iyen awon adije merindinlogbon (26) lojo Satide ati Sande to koja yi, ni won lawon kan ti n gbe iroyin naa kaakiri pe o see se ki Alao-Akala fi egbe naa sile.

A gbo pe Alao-Akala ti loo sepade po pelu awon agbaagba egbe oselu Africa Democratic Congress, ADC lati jade dupo naa labe egbe oselu won.

Lesekese tiroyin naa ti jade sita lawon eeyan ti bere sii gbe e kaakiri pe ki won ma fokan tan okunrin naa ju, nitori pe seku-seye lo n se lasiko yi.

Idi ni yii ti adari eka eto iroyin fun ipolongo e, Ogbeni Jeremiah Akanda fi gbe atejade sita pe iro nla to jinna si otito oro ni won n gbe kaakiri pe oga awon, Alao-Akala fe e fegbe naa sile.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI