EGBE OSELU PDP IPINLE EKO TI KU PATAPATA - SALVADOR - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, September 18, 2018

EGBE OSELU PDP IPINLE EKO TI KU PATAPATA - SALVADOR

IGBAGBOYEMI ESUPOFO

Ọnarebu Moshood Adegoke Salvador to ti figba kan jẹ alaga fẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Eko ko to darapọ mọ APC ti sọ pe ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo lo wa nipinlẹ Eko bayii, ohun naa si ni APC, nitori PDP ti ku patapata ti wọn si ti gbe wọn sin in.

Ọjọ Abamẹta, Satide, lo sọrọ yii lakooko ti wọn ṣayẹyẹ igbaniwọle sinu ẹgbẹ oṣelu tuntun, iyẹn APC, eyi to waye ni papa iṣere Agege niluu Eko.

Nibi ayẹyẹ ọhun, eyi tawọn ọmọlẹyin bii ẹgbẹrun mẹwaa ti wọn jẹ ti ọkunrin naa ti darapọ pẹlu ọga wọn yii ni Salvador sọ pe tẹlẹtẹlẹ ẹgbẹ oṣelu meji lo wa nipinlẹ Eko, APC ati PDP, ṣugbọn nigba tawọn to jẹ ojulowo ninu ẹgbẹ PDP ti fẹgbẹ naa silẹ, eyi tumọ si pe PDP ti ku, APC nikan lo wa.

O tun sọ pe erongba oun ninu ẹgbẹ naa ni lati ri i pe ida mọkandinlọgọrun un ninu ọgọrun un darapọ mọ ẹgbẹ naa ati pe o da oun loju pe ẹgbẹ naa yoo ni ibo miliọnu meji abọ fun ibo ipinlẹ ati miliọnu marun un fun ibo aarẹ, ninu ibo to n bọ lọdun to bọ.

Bakan naa lo gba awọn ara Ọsun nimọran pe ti wọn ba fẹẹ ki ilọsiwaju tubọ tẹ siwaju nipinlẹ naa ki wọn ri i pe wọn dibo fun ẹgbẹ APC ninu ibo to n bọ lọjọ Satide, ọsẹ yii. O ni ki wọn ma jẹ kawọn kan fọrọ didun tan wọn jẹ, nitori ko sẹni to ni eto rere fun wọn ju APC lọ.
https://mpulse.mtnonline.com/#utm_source=awikonko&utm_medium=banner&utm_campaign=mpulse

Salvador tun sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP kan si wa nipinlẹ Eko ti wọn ko nii pẹ darapọ mọ APC, nnkan to ni awọn yẹn kan duro de ni ibo pamari ti wọn fẹẹ di.

Ninu ọrọ Sẹnetọ Anthony Adefuye, to ṣoju Aṣiwaju Bọla Ahmed, O sọ pe inu awọn dun fun ayẹyẹ yii nitori pe nibi ti olori ẹgbẹ ba ti fẹgbẹ silẹ, eyi to tumọ si ni pe ẹgbẹ naa ti ku, o ni bo tilẹ jẹ pe aisun isinku onigbagbọ ẹgbẹ naa lawọn ṣe, ọjọ keji tii ṣe ọjọ Aiku, Sannde, lawọn yoo sin wọn patapata.


Ko to to akoko naa ni alaga ẹgbẹ oṣelu naa, Tunde Balogun, ti kọkọ gba Salvador atawọn eeyan ẹ kaabọ sinu ẹgbẹ APC pẹlu ileri pe awọn yoo fọwọsowọpọ pẹlu wọn, ati pe wọn ko nii kabamọ pe wọn darapọ mọ wọn.

Lẹyin ti Anthony Adefuye sọrọ tan, ni gbogbo awọn eeyan naa fa kaadi ẹgbẹ PDP to wa lọwọ wọn ya, ti wọn si daanu, ki  alaga ẹgbẹ ọhun to gbe asia ẹgbẹ naa le Salvador lọwọ pẹlu ijo ati ayọ.

LATI: BO SE RI

PÍN-IN KÁÀKIRI