Egbe oselu APC ko lenu nibe mo nipinle Ogun, PDP ni yoo wole lodun 2019 – Malik Ibitoye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, September 5, 2018

Egbe oselu APC ko lenu nibe mo nipinle Ogun, PDP ni yoo wole lodun 2019 – Malik Ibitoye

Alukoro fegbe oselu PDP nipinle Ogun, Alaaji Malik Ibitoye ti so pelu idaniloju pe egbe oselu naa ni yoo wole fun ipo gomina lodun 2019, nitori idi eyi ki Amosun atawon eeyan maa di eru won sile lati kuro nile ijoba.

 


O soro yii lakooko to n kopa nibi iforowanilenu wo kan, o so pe ijoba ti egbe oselu APC n dari lowo nipinle naa lo fee buruju tawon araalu si ti pinnu lati fi ibo le won danu. O fi esun kan Gomina Ibikunle Amosun lori bo se je pe opo awon ise akanse to n se lo fi si eya kan ju okan lo, ati pe awon igberiko to ti ye ko sise lee lori lo pa ti, ti ko si ye ko ri bee.

 

Bakan naa lo tun salaye pe opo awon igberiko lona won ti baje, tijoba to wa lode yii ko se nnkan kan lee lori eyi to si mu ki igbe aye le koko fawon olugbe ti won n gbe nibe. O tun so siwaju pe bijoba naa se n pariwo pe eto eko je awon logun, o lopo awon ileewe giga nipo ti won wa ko derun.

 

O fikun un pe ibanuje okan lo je pe bijoba Gbenga Daniel se fi awon ileewe naa si lo si titi di akoko yii.O ni lara nnkan ti Gomina tele to wa lati inu egbe oselu PDP se lori eko ki i se kekere. O ni bo se da ileewe Poli ICT sile lawon igun kookan nipinle Ogun bee lo tun rii pe agbega ba ileewe yunifasiti OOU, eyi to je tijoba ipinle bee lo tun sagbekale

 Yunifasiti mi in, iyen Tai Solarin to wa ni Ijebu Ode.

 

Bee lo so pe kekere lawon araalu  si n ri lawon ise akanse ti Onarebu Oladipupo Adebutu n se kaakiri ati pe bi won ba le dibo fun un ko wole sipo gomina lodun 2019 gbogbo eeyan ni yoo je mundunmundun e.

 

Malik Ibitoye tun so siwaju pe lara ise ti Ladi Adebutu to je onarebu nile igbimo asoju sofin niluu Abuja nibi to ti n soju ekun  Ikenne/Shagamu/Remo  ti se ni fi fun awon araalu ni tiransifoma ogorun un kaakiri ipinle yii, eyi ti ko tii sele ri.

 

O ni ‘Awa ti setan lati gbakoso lowo egbe oselu APC ninu ibo gomina to n bo lodun 2019, nitori gbogbo igba lawon araalu n so pe awon fee ayipada rere, igbe aye tijoba to wa lode yii n ko awon si ko te won lorun.o si da mi loju lodun to n bo awa la maa gbakoso Oke- Mosan lagbara Olorun’

 

Ibitoye tun so pe edun okan lo je pe Amosun ko pese ise fawon eeyan bo ti to ati bo se ye, bawon odo ko se nise ki i se nnkan to dara, gbogbo lo si ni Ladi Adebutu yoo sise lee lori to ba depo naa.

 

Bee lo ni oko gbese ni Amosun tun fojoojumo ko ipinle yii si nigba lilo maa yawo to je pe yoo to opo odun ki won to le san an tan sibe naa gbogbo owo ti won ya naa, ko si anfaani fomo ipinle ogun nibe.

 

O wa pari oro e oun nireti  pe ibo odun to n bo yoo lo nirowo-rose, tawon araalu yoo dibo yan eni to yoo tun igbe aye won se,ti yoo si mu ki nnkan rorun fun gbogbo won, iyen Ladi Adebutu ninu egbe oselu PDP.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI