Booda Agbaaya Fipa Fa Idi Omodun Metala Ya L'Ota - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, September 2, 2018

Booda Agbaaya Fipa Fa Idi Omodun Metala Ya L'Ota

Pelu bi nnkan se n lo ba yii, bi awon obi ko ba tete mura gidi soro awon omo won, ki won si maa mo iru eni ti won yoo maa fi awon omo won ti, o see se ki kawon apanilekun jaye tubo maa fi ojoojumo po si.


Ojo buruku gbomimu lojo Abameta Satide to koja yi je nigba ti Baale ile kan sakiyesi pe won ti n ba omo e omodun metala sun, ko da a, ti won ti fa idi e ya perepere.

Gege ba a se gbo, agbegbe Ota nijoba ibile Ado-Odo Ota, ipinle Ogun lo ti sele.

Omo naa la gbo pe o sadede yi iwa e pada lojiji, ti ko si sere bo se maa n se tele, bee ni kii jeun bo se n jeun tele mo, eyi ta a gbo pe o fu baba e naa lara.

Bo tile je pe omo naa ko koko fe e jewo, sugbon arewa ti won ni baba naa pa mo omo e lo je ko pada jewo pe booda kan tawon jo n gbe ile lo maa n fipa ba oun sun.

Omo naa ta a foruko bo lasiri so pe booda naa ti won pe oruko e ni Adewale Olakusi leyin to ba fipa boun sun tan, se lo tun maa n dunkoko moun pe oun yoo ku boun ba fi le so fenikeni.

Eyi lo mu ki baba naa gbera lo tesan olopaa to wa ni Onipanu lati loo fi ejo sun DPO, SP Sangobiyi Johnson, toun naa si ran awon omose e lati loo gbe Adewale.

Adewale la gbo pe ko koko fe e jewo, sugbon nigba ti omo naa bere sii soro niwaju e atawon ti won jo duro, lo too pada jewo pe looto ni, ati pe ise esu ni.

Loro kan sa, Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu ti bu enu ate lu iwa naa to si pase pe ki won si fi Adewale pamo si ahamo eka ileese won to n ri si lilo awon omode nilokulo.

Bee lo gba gbogbo obi atawon alagbato lamonran lati maa sabojuto awon omo won daadaa, ki won si ma se gbekele awon ti won n fi awon omo won so, nitori pe eni abinibi n da ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI