Baba Agbalagba Pokunso Sori Igi Koko Nitori Ko Ri Owo Ko Ile - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, September 12, 2018

Baba Agbalagba Pokunso Sori Igi Koko Nitori Ko Ri Owo Ko Ile

Gbogbo awon ti won ri baba agbalagba kan ta a ko tii moruko e dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan nibi to pokunso si lori igi koko (cocoa) ni won gbera sanle, ti won si n banuje gidigidi.


Baba agbalagba naa ta a gbo pe omo bibi abule kan ti won pe ni Ikot Akpan Ikpong ni Afaha Obong nijoba ibile Abak, ipinle Akwa Ibom ni la gbo pe ojo Sande to koja yi lo lo sile won.

Ilu Oron nipinle naa la gbo pe o n gbe, iyen nibi to ti n sise e, sugbon irole ojo Sande naa la gbo pe o pinu lati yoju si ilu won.


Ko pe ti won loo de ile won la gbo pe o loo gbategun labe igi koko (cocoa) to maa n jokoo si gbategun, legbe ile egbon e.

AWIKONKO gbo pe igba ti won lawon ebi e to wa a kii ko tete rii pe ko pada wole ni won bere sii wa kaakiri, to si je pe nigba ti won maa rii, oku e ni won ri lori igi to n min jolon-jolo.


Ariwo ikunle abiyamo lo gba enu awon eeyan kan nirole ojo naa, ti won si ni awon olopaa ni won pada wa a gbe oku e kuro.

Lara awon to fisele naa to AWIKONKO leti je ko ye wa pe se ni okunrin naa ronu gbemi ara e nitori pelu bo se n sise to, ko ri owo tujo lati fi ko ile ara, to je pe se lo n ya ile gbe.

Eni naa lo tun je ko ye wa pe ko too di pe baba agbalagba yi gbemi ara e, o ti ba foonu e je, o si tun ti gbe kaadi pelebe ibanisoro, iyen simcard e je, kawon eeyan ma baa rii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI