Oku odaran naa |
Ipinle
Eko la gbo pe moto naa ti n ko awon eeyan lo rin irinajo lo sile Yibo, ki won
lawon adigunjale to da won duro lagbegbe Ogbere lopopona Sagamu si Benin.
AWIKONKO
gbo pe nibi ti won ti le gbogbo won bo sile lati maa a fibon ba eru won lawon
kan to n koja lo ti tawon olopaa lolobo, tawon yen anaa si teko leti de be.
Won ni
bi won se foju kan moto awon olopaa ni won koju ibon si won, ti won si bere sii
yinbon funra won, nibe la gbo pe ibon ti ba eni kan ninu won, to je pe esekese
lo ku.
Bi won
se lawon to se rii pe ibon ti ba okan lara won to da bii pe oun lo lewaju won
loo jale naa, lo mu kawon to ku ba ese won soro, ti won na papa bora.
Komisana
olopaa, Ahmed Iliyasu to fidi isele naa mule fi idunnu e han lori bi won se pa
okan lara won, to loun ti pase pe ki won tete wa awon odaran to ku ri nitori pe
ara oun ko le gba a lati maa ba odaran gbe inu ilu kan naa.
Awon
ohun ija oloro bii ibon, ayderu ibon kekere ati oogun abenugongo la gbo pe ri
gba lara odaran ti won pa danu naa.