Agbarijo gomina labe asia egbe oselu PDP lorileede Naijiria ti so o sita pe awon ko nigbagbo ninu ajo eleto idibo, iyen INEC latari eto idibo to n bo lona lodun 2019.
Won ni awon ko nigbagbo pe ajo naa le dari eto idibo to n bo yi lai fi igba kan bo okan ninu, nitori pe ajo naa ti gbabodi lati jowo ara e fun isakoso egbe oselu APC.
Awon gomina naa tun fesun kan alaga ajo INEC, Ojogbon Mahmud Yakubu ati Komisana lapapo fun ajo naa, Arabinrin Amina Zakari pe won lowo ninu ojusaaju ti ajo naa n se.
Lale ojo Sande to koja yi ni gbogbo awon gomina egbe oselu PDP naa sepade niluu Abuja, ti won si pari e laaro kutu ojo Monde ana nilegbe Gomina ipinle Ekiti, Ayodele Fayose to lagbegbe Asokoro.
Nibe ni Gomina Fayose ti towo bowe ipade ti won se, iyen communiqué pe awon ko nigbagbo ninunajo naa mo, paapaa lori awon igbese ti won n gbe latari eto idibo apapo to n bo lona.
Bi atejade naa se te ajo INEC lowo lawon naa ti sare soro sita pe bawon egbe gomina PDP ko ba nigbagbo ninu awon, iyen ko tunmo si pe gbogbo omo Naijiria ko nigbagbo ninu ise tawon n se.
Ninu atejade ajo naa ti akowe iroyin ajo naa, Ogbeni Rotimi Oyekanmi bu owo lu lo ti je ko di mi mo pe latigba ti isakoso ajo naa ti bere ninunosu kokanla odun 2015 lawon ti n rii pe eto idibo n lo bo se ye ko lo, tawon si n se awon ohun amuye to le.je kawon araalu kan saara si won.
No comments:
Post a Comment