AWON EGBE KAN LAWON YOO SATILEYIN IBO EGBERUN LONA OGORUN FUN APC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, September 11, 2018

AWON EGBE KAN LAWON YOO SATILEYIN IBO EGBERUN LONA OGORUN FUN APC

Latigba ti egbe oselu APC nipinle.Ogun ti kede Onarebu Adekunle Abdul-Kabir Adekunle gege bi adije sipo gomina labe egbe oselu naa lodun 2019, opo awon egbe ni won ti won ti bere sii gboriyin fun egbe oselu naa, ko da a, ti won tun n jeje pe awon yoo sagbateru won lasiko idibo.


Idi ni yii ti egbe kan ti won pe ara won ni Leagues of National Patriots se so pe awon ko ni ko nnkan ti yoo na won lati satileyin ibo ti ko din ni egberun lona ogorun (100,000) fun egbe oselu APC, paapaa Onarebu Akinlade ko le di gomina.

Leagues of National Patriots je egbe kan to n sagbateru awon egbe oselu lorileede Naijiria, o ti le lodun die ti won ti da a sile, topo awon eeyan si fowo soya lori won pe won kun oju osuwon.

Bakan naa ni egbe naa tun je egbe to n wo bi nnkan se n lo si ninu eto isejoba, ati lati rii pe iya ko je awon araalu, paapaa awon oludibo lati rii pe won je mudunmudun eto oselu awaarawa.

Nigba to n soro, Onarebu Adekunle Akinlade ti amugbalegbe e, Ogbeni Henry soju fun lojo naa dupe gidigidi lowo won fun ileri ti won se naa.

Bee lo so pe oga oun, Onarebu Akinlade yoo tele awon ipa ati ilana ti Gomina Amosun ba fi sile, paapaa ti yoo tun tesiwaju awon ise to ba se ku.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI