...Bee ni adajo pase pe ki won fi Alaaji Deikola atawon ti won so sewon sile
Titi di bi e ti n ka iroyin yi, inu iberubojo lawon eeyan ipinle Osun, paapa awon ara ilu Osogbo wa lati ale ana, Tusde pelu bi won se so pe ogunlogo awon sọja se n ya wonu ilu.
Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo lai pe yi se so, won lohun ti awon eeyan koko n ri ni pe awon olopa alaso dudu pelu awon olopa kogberegbe ti won sise aabo lasiko idibo gomina to waye lopin ose to koja n kuro ninu ilu laaro ojo Tusde si irole ojo naa.
Ko pe rara ni oniruuru moto awon soja n wole, titi di aaro yii ni won si n gba gbogbo ona wonu ilu Osogbo logun-logun, logbon-logbon, tawon eeyan ko si siye meji pe atundi ibo ni won wa fun un.
Idi niyii tawon araalu fi n foya, ti won n so pe se lo dabi eni pe awon ologun n mura wahala sile de atundi ibo ti yoo waye lawon woodu meje ti ajo eleto idibo so pe idibo ko pari nibe.
E o ranti pe lati ojo Monde ose yii lawon egbe oselu mejeeji ti won loruko ju ninu awon egbe oselu mejidinladota to kopa ninu eto idibo naa ti n fi esun toogi kiko kaakiri kan ara won.
Awon ibi ti atundi ibo yoo ti waye ni Osogbo, Orolu, Ariwa Ife ati Gusu Ife.
Ninu iroyin min in lati gbo pe ile ejo giga kan niluu Osogbo ti pase pe ki awon olopaa fi Alaaji Fatai Oyedele Diekola ti won ti ti mole lati ojo Monde sile.
Gege bi adajo ile ejo naa, Onidajo A. O. Ayoola se so, aibowo fun etọ omoniyan ni bi won se ti Diekola atawon meji miin, Adekilekun Segun ati Sikiru Lawal mole lai nidii.
Agbejoro Bukola Onifade lo gbe ileese olopa lo sile ejo. Adajo si pase pe ki won fi awon meteeta sile, ki won mase daamu won mo.
Ojo Monde lawon olopa so pe awon ba kaadi idibo alalope to to aadota lowo Diekola, latigba naa ni won ti ti won mole.
No comments:
Post a Comment