ALATENUJE ATI ALAIMOORE NI WASIU AYINDE - OBESERE SOKO ORO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 20, 2018

ALATENUJE ATI ALAIMOORE NI WASIU AYINDE - OBESERE SOKO ORO

ABIMBOLA ABERUAGBA

Gbajugbaja osere fuji omo ile yii, to tun je omo orile-ede Britan, Alaaji Abass Akande Obesere ti bu enu ate lu bi gbajumo osere fuji mi-in, Alaaji Wasiu Ayinde, ti won n tun pe ni K1 se da si wahala to n sele ninu egbe oselu APC ipinle Eko lori eni ti yoo jade gege bii gomina labe egbe naa ninu ibo odun to n bo, laarin Gomina Akinwunmi Ambode ati Ogbeni Jide Sanwo-Olu.


Obesere, ti won tun n pe ni Ologbojo so pe bi Wasiu Ayinde se ba awon kan bu Ambode yii, iwa e ko yato si odale ati alaimoore, nitori pe Ambode ti soore fun un daadaa, ko si ye keeyan ge ika to ti fun un lounje je.

O ni gbogbo aye lo mo pe asiko adanwo lasiko yii je fun Ambode, ko waa ye ko je iru Wasiu Ayinde to ti janfaani lodo gomina Eko ni yoo pelu awon eeyan ti won n gbogun ti i bayii. Obesere ni ohun ti K1 se yii ti sapejuwe e bii abanije ati arije nidii madaru.

"Mo fee fi da yin loju, mo si fe ki kinni kan ye yin in pe mi o ki i se ota Wasiu Ayinde, sugbon awon iwa to ti hu lati odun yii wa ni ko je ki eledaa mi ba a se, emi o ki i n ba afibisoloore tabi odale se.

"Gege bii olorin, gbogbo wa la lanfaani lati te le oloselu to ba wu wa, sugbon ohun to buru pupo ni ki olorin waa jade lati maa ba oruko oloselu kan je nitori owo.

"Ohun to n sele l'Ekoo yii, oro oselu ni, ki Wasiu fi awon oloselu sile, ki won yanju ohun to wa laarin won, sugbon bi Wasiu Ayinde se bere ogun ojiji pelu Ambode ko bojumu rara.

"Se e mo pe bi Wasiu Ayinde se fibi su oga wa, Alaaji Oloogbe Sikiru Ayinde Barrister niyen, to jade lati ta ko o, bo se kan baba wa Alaaji Kolligton Ayinla naa labuku niyen, ki i se eni teeyan le e fokan tan rara.
Iru iwa odale to hu si Ambode yii lo n fa ija laarin wa lati odun yii wa, nitori e ni mi o se le e ba a se laye, emi ki i ba odale ati alaimoore se ni temi.

"Mo fe ki Wasiu Ayinde mo pe ohun ti i tan lodun eegun, iyan ogun odun si ma n jo eeyan lowo, ti Ambode la ri loni-in, Olorun nikan lo mo eni ti yoo kan lola."

Won yi loro ti Obesere ba akoroyin kan so niluu Eko

PÍN-IN KÁÀKIRI